Home / Art / Àṣà Oòduà / Won o je ki Saraki o rona gba leyin to fun awon minisita Buhari lona lo
Saraki

Won o je ki Saraki o rona gba leyin to fun awon minisita Buhari lona lo

Olayemi Olatilewa

Ile ejo kotemilorun to kale siluu Abuja ti da esun aare ile igbimo asofin agba, Bukola Saraki nu patapata. Ninu esun ti Saraki gbe lo si ile ejo, ibe ni Saraki ti n ro ile ejo lati pase jokoo-jee fun  Code of Conduct Tribunal (CCT) latari awuyewuye ti won gbe dide. Bakan naa lo n wi pe ki ile ejo naa da gbogbo esun ti tiribuna gbe kaa laya nu sinu omi okun agbadagbudu. Sugbon sa, kaka ki ile ejo se ohun ti saraki n pe fun, iwe ofin ni ile ejo si ti won si kaa seti gbogbo mutumuwa. Won ni Code of Conduct Bureau ni ase labe ofin lati gbe enikeni lo si ile ejo tiribuna nigba to ba ye fun won lati se bee ninu ise won.

 

Saraki ni won fi esun metala kan eleyii to dale aisododo nipa ijewo dukia eni ati awon iwa jegudujera ni awon akoko to je gomina ipinle Kwara. Nibayii, ile ejo to gaju niluu Abuja ti pase fun Code of Conduct Tribunal (CCT) lati maa ba awon esun metala ti won fi kan Bukola saraki lo lai si idiwo tabi idina kankan.

Iroyin tuntun yii lo jade lojo Eti to koja yii leyin ti Saraki ati awon senato yoku fi ontelu lu awon minisita Buhari, paapa julo, Rotimi Amaechi ti awon kan ti ni ko ni yege.

Ti e ko ba gbagbe, ojo karun-un ati ojo kefa osu kokanla odun ta a wa yii ni ile ejo tiribuna yoo tun maa pada jokoo lati ye Saraki wo bi igba ti tisa ba n gbon ise akekoo wo yebeyebe.

Lori esun jegudujera kan naa, ile ise ti n risi iwa idaran niluu London, National Crime Agency [NCA] si n ba iwadii won lo ni rebutu nipa minisita epo robi ile Naijiria nigba kan, Arabinrin Diezani Alison-Madueke lori awon esun jegudujera ti won fi kan-an.

Bi o tile je wi pe awon agbofinro ilu London ti pada tu Madueke sile ko maa lo sile, sugbon gbogbo iwe irinna re pata ni won ti gba lowo re. Eleyii ti ko fun lanfaani lati tirafu jade niluu London titi ti gbogbo iwadii ti won se yoo fi kesejari.

Nibi ti Madueke, obirin akoko ti o je aare egbe awon orileede ti won ti n fo epo-robi lagbaye, Organization of the Petroleum Exporting Countries (OPEC), ti n ronu kini o le je abajade iwadii awon olopaa ilu London, Abba Moro o loju orun mo pelu bi Aare Buhari se siwe iranti kan-an.

Boya eyin gbagbe, losu keta odun 2014, awon eniyan bi ogun, awon odo, ni won doloogbe nibi won ti n lakaka lati rise gba ni eka ile ise ijoba apapo to n risi wiwole-wode, Nigerian Immigration Service.

Abba Moro lo je minisita feto abenu nigba naa, to si je eni  ti oro naa kan gbongbon, ni awon ara ilu pe fun idaduro re lenu ise. Sugbon aare to wa nipo nigba naa, Goodluck Jonathan, foju fo asise re da.

Asiri to tun tu nigba naa ni wi pe won fi eto igbanisise naa kowo je eleyii ti won ni kan dapada sugbon ti won ko lati se bee.

Awon Yoruba bo, won ni iyan ogun odun a maa jo ni lowo felifeli.

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Saraki

Saraki Tackles Buhari, Says Eighth Senate Organised Security Summit

Former President of the Senate, Dr. Bukola Saraki, yesterday faulted the claim by President Muhammadu Buhari that the Eighth Senate did not assist his administration to battle insecurity by organising a summit to generate ideas on what to do.Saraki’s media aide, Mr. Yusuph Olaniyonu, said in a statement yesterday that the immediate past president of the Senate, noted with dismay the claim contained in the seventh paragraph of a statement on Tuesday, by Buhari’s media adviser, Mr. Femi Adesina, that ...