Home / Art / Àṣà Oòduà / Manchester United Ti Se Tán Láti Ra Odion Ighalo Pátápátá
Ighalo

Manchester United Ti Se Tán Láti Ra Odion Ighalo Pátápátá

Manchester united ti se tán láti ra Odion Ighalo pátápátá

Lati owo Akinwale Taophic

Se won ni ti egungun eni ba jo re, ori a ma ya atokun re. Ati wi pe, Ku ise ni n mu ori eni ya! Gudugudu meje ati yaaya mefa ti atamatase fun orileede wa Nigeria ni igba kan ri, eni ti o darapo mo iko Manchester United ninu osu kini odun ti a wa yi pelu adehun alayalo lati inu iko egbe agbaboolu Shanghai Greenland Shenhua, Odion Jude Ighalo, n se lowoyi ninu iko naa ko ni afiwe rara, boya idi re niyen, ti awon alokoso iko naa labe oludari won keji, Ed Woodward, se fi ife han lati gbe patapata pelu owo ti o to milionu meedogun poun (£15 million) owo ile okere.

Gege bi oro olukoni fun iko naa, Ole Gunnar Solskjear, o je ki o di mimo wi pe inu oun dun si gbogbo isowo gba boolu Odion Ighalo, ati wi pe ohun ti o da oun loju ni wi pe ti awon ba fun ni aye, yio tun se ju bee lo.

Se laipe yi ni Manchester United fi iroyin sita wi pe awon ni ife lati gbe atamatase omo orileede wa Nigeria miran ti o n gba boolu ninu iko Lille ni orileede France, Victor Oshimen, sugbon ti awon alokoso iko naa taku jale wi pe aadorin millionu poun owo ile okere (£70 million) ni awon yio gba lori omo naa.

Lati igba ti Oshimen ti darapo mo iko egbe agbaboolu Lille, koteti rara, o ti gba ifigagbaga ti o to mejidinlogoji (38 appearances) fun won, o si ti gba ami ayo mejidinlogun (18goals) wole pelu iranlowo (6 assist) mefa. Metala ninu awon ami ayo re ni o gba wole ninu ifigagbaga metadinlogbon ninu liigi akoko orileede France.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Quadri Akinade Aruna vs Hugo Calderano

Quadri Akinade Aruna vs Hugo Calderano | MS R16 | WTT Finals Men Doha 2023