Home / Art / Àṣà Yorùbá / Ẹ̀FỌN

Ẹ̀FỌN

Ẹ̀FỌN
Oníyánmú ń pa yánmú, oníyànmù ń pa yànmù, Ẹ̀fọn ń se yún-ùn yún-ùn
L’étí ọmọ adáríhurun.
Ẹ̀fọn kìí sùn bẹ́ẹ̀ni kòní jẹ́ k’ẹ́ni orun ń kùn ó sùn.
Ẹ̀fọn ń gbọ́ pà
Ẹ̀fọn ń gbọ́ pò
Ìjùbàlà lọ́tùn-ún
Ìjùbàlà lósì
Ó sebí adáríhurun ń pàtẹ́wọ́ fún òun ni.
Ó rò pé ọmọ ádámọ̀ ń f’átẹ́gùn fún òun ni.
Ó dijọ́ tí a bá t’ìlẹ̀kùn gbọin-gbọin
Tí a fín tábà
Tí a fín tùràrí
T’ẹ́mọ́ ò leè jáde l’ópòó
T’ókèté ò leè jáde nísà
T’áfèrèmọ̀jò ò leè jáde l’ókìtì.
Ìgbà náà lẹ ó mọ̀ gbangba gbàngbà wí pé ọwọ́ t’ọ́mọ aráyé ń pa f’ẹ́fọn
T’ẹ̀rín kọ́
T’ẹ̀fẹ̀ kọ́
Wọ́n fẹ́ sekú pa ẹ̀fọn ni
Nítorí ẹ̀fọn ń t’ẹfọ̀n láyà.
Mo mèdè
Mole pèdè
Mo mẹ̀sọ̀ èdè
̣Ẹni ọmọ aráyé bá ń pàtẹ́wọ́ fún, kó máse jó yàgín ní
Torí báyé bá ń pani l’ẹ́rìn-ín
Wọn a tún máa pani lẹ́kún jọjọ,
Mo kí gbogbo ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi òkè òhún
Àti pèdèpèdè, àti pàsàpàsà, àti adákẹ́fọwọ́mẹ́kẹ́.

Send Money To Nigeria Free

About Awoyemi Bamimore

2 comments

  1. Olanabbey

    Igi wórókó tó ń da iná rú. 🤧

x

Check Also

Olójòǹgbòdu: The Wife of Death.

Sculpture at the Àkòdì Òrìṣà, Ile Ife, Nigeria