Home / Art / Àṣà Yorùbá / Ọdún orò gbìnà yá, ìdájí ní àwọn olórò yóò fi máa yíde ìlú níṣẹ̀yin

Ọdún orò gbìnà yá, ìdájí ní àwọn olórò yóò fi máa yíde ìlú níṣẹ̀yin

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣe aifẹsọ kebosi,lai rẹni jo o,ati pe n ta o ba fẹ o bajẹ,o ni bi o ṣe yẹ ka ṣe e,eyi lo bi atunse abẹnu lati fopin sawuye wuye to waye latari aawọ to suyọ laarin awọn onisese ati awọn ẹlẹsin meji ti o ku(Kitẹẹni ati Musulumi).
Wayi o, igbakeji alaga fun ẹgbẹ agbaagba nilu Isẹyin, Alhaji Bọlaji Kareem, ti kede pe ija ti dopin, ogun si ti tan lori aawọ ọrọ sise nilu Isẹyin.
Kareem, ẹni to soju Asẹyin nibi ipade ipẹtu saawọ kan ti ẹgbẹ agbaagba naa seto salaye pe, lasiko to n ba lroyin Owurọ Yoruba sọrọ ni, awọn igbimọ Imaamu ati Alfa nilu Isẹyin, to fi mọ ẹgbẹ ẹlẹsin ọmọlẹyin Kitẹẹni,CAN atawọn
abọrẹ oro mẹrẹẹrin nilu naa, lo peju sibi ipade ọhun.

Nibi ipade naa lo ni wọn ti fẹnu ko lati jẹ ki ogun o sinmi, ti awọn oloro yoo si maa se oro wọn lati aago marun aabọ irọlẹ si marun idaji, ti wọn ko si ni yaju si ẹnikẹni.
Bakan naa, etutu oro ti gbera nilu Isẹyin lọjọ Aje pẹlu bibẹ aja sidi Ogun to wa loju ọja ilu naa.

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

O̩kùnrin àkó̩kó̩ lórí Te̩lifísò̩n l’Áfíríkà filè̩ bora

Bí Kunle Ọlasọpe, ìlúmọ̀ọ́ká agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ṣe lo ìgbésí ayé rẹ̀ rèé o. Fẹ́mi Akínṣọlá Àwọn àgbà bọ wọ́n níjọ́ a kú,làá dère,èèyàn ò sunwọ̀n láàyè. ọrun dẹ̀dẹ̀ má kánjú gbogbo wa la ń bọ̀.Olóògbé Kunle Ọlasọpe, tíí ṣe ọkunrin akọkọ to fi oju han lori i amóhùnmáwòrán ti waye, o si ti lọ, a mọ iṣẹ́ ẹ rẹ̀ ń tọ́ọ̀ lẹ́yìn.Ọjọ Aiku, ọjọ Kẹfa, Osu Kẹwaa, ọdun 2019 ni gbajúgbajà agbóhùnsáfẹ́fẹ́ naa, Kunle Ọlasọpe sílẹ̀ bora lẹni ọgọrin ọdun.Ó ní ...