Sáká lára dá,Bàbá Ọbásanjọ́ kò l’árùn Kofi-19
Fẹ́mi Akínṣọlá
Agbẹnusọ fún Bàbá Ọbásanjọ́, Kehinde Akinyemi ló fi léde bẹ́ẹ̀ nínú àtẹjáde ní Ọjọ́ Ìsinmi pé àyẹ̀wò fihàn pé kò ní àrùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì.
Akinyemi ní Ọjọ́ Keje, Oṣù Kẹjọ, ọdún 2020 ni bàbá ṣe àyẹ̀wò fún àrùn Kofi-19 ní ilé rẹ̀ tó wà ní ilé ìkàwé Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́ Presidential Library (OOPL) Pent House residence, Okemosan, Abeokuta, ní ìpínlẹ̀ Ògùn.
Wọ́n fikún pé Dókítà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olukunle Oluwasemowo ti iléèwòsàn Molecular Genetics Laboratory 54gene, nípìńlẹ̀ Èkó ló ṣe àyẹ̀wò náà.
Àbájáde àyẹ̀wò náà ní Ọjọ́ Ìsinmi, Ọjọ́ Kẹsàn án, Oṣù Kẹjọ ló fi léde pé sáká ni ara Bàbá dá lọ́wọ́ àrùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì.
.Iléèwòsàn tó ṣe àyẹ̀wò náà wà lára àwọn iléeṣẹ́ àyẹ̀wò fún àrùn Kofi-19 to gba òǹtẹ̀ Ìjọba àti àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn ní Nàìjíríà, NCDC.