Home / Art / Àṣà Oòduà / Awon Foto Alaafin Oyo niluu London
Alaafin

Awon Foto Alaafin Oyo niluu London

Alaafin ti bere ayeye odun marunlelogoji (45) lori oye pelu idije ese kikan niluu London

Olayemi Olatilewa

Oba (Dr) Lamidi Olayiwola Atanda Adeyemi III ti bere ajoyo ayeye odun marunlelogoji (45) to gori ite awon baba nla baba re lode Oyo. Ayeye yii to ti bere lojo kinni osu kejila odun yii niluu London, nigba ti asekagba re yoo maa waye laafin Oba Lamidi lojo kerinla osu kini odun to n bo nibi ti awon oba alaye kaakiri ile kaaaro-o-ji-i-re yoo ti ma ye baba si pelu aimoye olorin ibile.

 

Ayeye odun marunlelogoji yii lo ti bere niluu London lojo kinni osu yii ni kete ti Alaafin wo ilu London pelu omo re, Omooba Akeem Adeyemi. Aimoye awon omo Yooba pelu awon osise ile ise asoju ile Naijiria ti won wa niluu Oba ni won tu jade lati se ayesi oba to je leyin ti Gbadegesin Ladigbolu II goke aja. Lati papako ofurufu ni awon eniyan ti kowo rin lo si ile Alaafin, ile alarambara to duro ganga soke, eleyii to kale si Marlin Statford, 2 Millstone Close nigboro ilu London.

Aimoye orisiirisii eto ti won la kale fun ayeye yii ni won ti n fowo ba lokookan ejeeji lati ojo kinni osu yii ti omo Adeyemi Adeniran ti wolu obabirin Elisabeeti. Lara won eto naa ni idiji ese kikan oloresore laaarin Oba Lamidi ati Larry Ekundayo, ogbontarigi omo Naijiria afeseku-bi-ojo, eni to gbe ami eye African Boxing Union Welterweigh dani. Leyin ere idije naa ni Larry gbe ami eye re to gba naa fun Alaafin lati fi saponle re fun ayeye odun marunlelogoji to pe lori oye.

Bakan naa Oba Lamidi farahan lori Sky Sport Studio, Ben Television ati Oodua Voice Radio nibi to ti n ro awon omo Yoruba ti won gbe niluu Oba lati ma so omoluabi won nu. Bakan naa lo tun ro won lati ma gbagbe orisun won eleyii to je ojulowo ju lo.

Gege bi akosile itan ilu Oyo se so, ojo kejidinlogun osu kokanla odun 1970 ni Oba Lamidi de ade oba ilu Oyo nigba ti alase Western Region nigba naa, Colonel Adeyinka Adebayo fi opa ase le e lowo lati maa dari ilu Oyo. Oba Olayiwola, eni odun metadinlogorin (77), ni yoo si je oba eleeketalelogoji (43) ti yoo je Alaafin ilu Oyo.

Gege bi oro Omooba Akeem Adeyemi, omo Alaafin Oyo, eni to tun je okan lara awon omo ile igbimo asoju-sofin l’Abuja se so, o ni ayeye odun marunlelogoji oba Lamidi lori oye eleyii to bere niluu London dabi igba ti eniyan ba woran mariwo lasan. “Mariwo leleyii, egungun to je baba mariwo ni eyi ti o sele lode Oyo lati fi ye baba si. Baba je eni kan to lemi ifinsi ati ododo, eleyii si wa lara awokose rere fun iru awa,” Hon Akeem ti gbogbo eniyan mo si Skimeh lo so bee.

Omooba Akeem, eni to n duro bi olowo-otun Ikubabayeye niluu London tun fi da awon eniyan loju wi pe, awon akowe iroyin baba yoo tun maa kede laipe nipa awon eto ti yoo waye nigba ti Alaafin ba pada wale. O ni aimoye eto lo ti wa nikale, eleyii ti yoo si maa lo titi ti asekagbe re yoo fi waye lojo kerinla osu kinni odun ti n bo.

Alaafin

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti