Òrìsà Bayani.
Òrìsà alágbára yí ni òrìsà omodé tí a bí pèlú dàda . Ó dára kí a ma bo òrìsà yí kí á sì ma bèèrè fún ìdábòbò, kí á b’orí òtá àti gbogbo ire ilé ayé.
Gbogbo ènìyàn ni ó le bo òrìsà yí, ó ń bá orí rìn ìdí ni yí tí a fi máa ń bo ó ní ilé-orí.
Òrìsà kórì
Èyí ni òrìsà omi fún èwe; ó ń dá ààbò bo èwe nínú ewu ayé, ikú òjijì pèlú jàmbá abbl. Ó tún dára fún àgbàlagbà kí a bo ó fún èmí gígùn, oríre àti ìdábòbò. Gbogbo abiyamo ló gbodò bo òrìsà kórì láti bèèrè fún ìdábòbò omo won. Ó ń bá egbé rìn a sì le bo ó nínú kòkò egbé òrun.
Òrìsà olúbòbòtiribò Baba enu
Èyí ni òrìsà enu; ó dára láti bo ó fún eni tí ó ń wá ìdábòbò lórí èsùn ,enu ní agbára ńlá; agbára láti fún je, s’òrò, to wò, Kì í se gbogbo agbára rè ló da; o tún le s’épè pèlú enu re, o le ní èsùn kí o sì se èèyàn. Ìdí àtakò rè é tí ó fi ye kí á bo òrìsà yí kí a si fún ohùn rere nìkan kí òrò tí yóò ma jáde l’énu wa láì gba èsè àti èsùn láàyè.
Òrìsà olúbòbòtiribò Baba a gbodò ma bo ó pèlú ayeye, tí a bá sì ń bo ó ounce gbodò wà fún àwon ènìyàn láti je. Inú kòkò ni a ti ń bo olúbòbòtiribò Baba enu….
Continue after the page break for English Version