Home / Art / Àṣà Oòduà / Ewu to wa ninu foonu lilo ati pataki ilera wa

Ewu to wa ninu foonu lilo ati pataki ilera wa

Opolopo wa ni a n lo foonu ni aye ode oni, sugbon ti a kosi mo awon ewu keekeke to ro mo o eleyii to le se ipalara fun ago ara wa.

E je ka ri daju wi pe a n nu foonu wa lorekoore. Paapaa julo, ti a ba lo foonu wa ni akoko ti a ba n laagun pupo. Orisiirisii kokoro aifojuri lo le jeyo latari aagun to gbe mo ara foonu wa eleyii ti a tun pada gbe seti. Bakan naa, awa ti a ni omo ikoko nile, e ma je ki awon omo wa maa fi foonu wa sere debi wi pe, won yoo ma ponla lati fi senu.

Ewu nla wa ninu ki foonu maa gba agbara lowo ni akoko ti a ti bona, ki a tun ma wa fi iru foonu bee pe lai yo kuro ninu ina. Ti a ba n saaji foonu wa lowo, ti ipe ba wole, e je ki a yo kuro ninu ina ki a to gbe ipe naa.

Awon kan tun feran lati maa fi earpiece seti sun lo, awon nnkan bayii lewu. E si je ka yago fun opolopo ariwo to le se akoba fun eti wa ni akoko ti ba n lo earpiece lati gbo orin. Awon kan tile so wi pe, ka maa lo earpiece eleti kan dara ju eleti meji lo. Eleyii yoo fun yin laaye lati gbo ohun ti aye so ni akoko ti e gbo orin lowo.

A ti wi pe, ti eti kan ba ti n ta yin, e le paaro si eti keji. Pupo ninu awon iyaloja feran ki won maa fi foonu pamo si aarin palapolo igbaaya won. Asa bayii ko dara, o lewu fun ilera. Ti e ba fi foonu si igbaaya ti ipe ba wole, ti foonu naa ba wa ni gbigbonriri (vibration), o le se akoba fun okan yin.
E si je ka soro nipa gbigbe foonu saya sun lo tabi didaya le foonu sun mole.

Awon iwadii oke yii la se lati owo awon osise alaabo ilera, yoo si se yin lanfaani ti e ba le samulo re gege boti ye. Alafia wa ko ni di fiafia.

Ase !

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

balogun ilu yoruba

Remembering Famous Balogun (Generals) of Yoruba Land.

1) Balogun Oderinlo of Ibadan – Conquered the Fulanis in Osogbo.2) Balogun Ibikunle of Ibadan – defeated the treacherous Aare Ona Kakanfo Kurumi of Ijaye.3) Balogun Akere of Ibadan – died while fighting against the Ijesha army in the Kiriji war.4) Balogun Orowusi of Ibadan – defeated the Ijesha army.5) Balogun Ogunbona of Egba land – conquered the Dahomey army.6) Balogun Osungboekun of Ibadan – replaced Latoosa in the Ekiti Parapo/Kiriji war.7) Balogun Olasile of Ijaye – served and died ...