Home / Art / Àṣà Oòduà / Iwon ese bata kan pere: E kaabo sinu osu tuntun

Iwon ese bata kan pere: E kaabo sinu osu tuntun

#Ogulutu #4

Eyin eniyan mi, n maa ki yin kaabo sinu osu tuntun pelu itan Ogbeni Darby omo ilu Amerika to ti n tawo-tase ninu mi fun igba pipe. Itan aroko ko, bee si ni mi o ni fe ki e fi oju sinima agbelewo wo o. Lai moye odun seyin, Darby nife si ise iwakusa.

Leyin iwadii ati ifinmu finle re, o to ipase goolu lo si awon agbegbe kan ninu igbo kijikiji. O ko oko atada dani, bee lo bere si ni gbele. Igba to gbe de aye kan, o fura wi pe goolu mbe ni ogangan ile to n gbe fun ayewo.

Sugbon oro naa koja ohun to le fi oko atada wu jade. O pada sile lo ba awon eniyan re, o salaye wi pe ohun ti sewari ibi ti eniyan ti le ri goolu wa jade. Won lo yawo ra awon moto agbele ati awon irinse iwakusa, eleyii ti won yoo lo lati fi wa awon goolu naa jade.

Akiyesi Darby ko tase rara nigba ti won de ori ile naa, won ri goolu wa jade. Iwonba eyi ti won ri ti san gbogbo gbese ti won je sorun. Darby pinnu lokan re wi pe awon goolu ti awon ba tun ri wa jade lati akoko yii lo ni yoo je ere ajemonu f’awon naa.

Subon leyin eyi, gbogbo ile ti won gbe, won o ri goolu kankan mo. Won gbele-gbele, won ko ri ohun to jo ohun ti won wa. Won tun gbiyanju bi eni wi pe goolu naa si n be nisale, pabo naa ni gbogbo re jasi.

O su Darby, o ko gbogbo irinse ti won ra ta, o si gbale lo. Okunrin to ra awon irinse naa gba ibi ti won ti sise pati lo. Igba to de be, o pe awon onimo nipa alumooni ile lati wa se ayewo ile naa boya ohun gidi kan si tun seku nibe.

Igba ti won yoo se ayewo ile naa, won ri wi pe iwon ese bata kan pere loku ti won yoo fi kan obitibiti goolu ogidi alainiye. Okunrin yii lo jifa naa, o ko aimoye goolu alailonka, o si dibe di olowo tabua.

Opolopo awon eniyan ni irewesi ti deba ti won si ti pada ninu igbiyanju won bi odun se n pari lo. Ti e ba pada, elomii ni o ko yin nifa.  Iwon ese bata kan pere lo ku fun yin lati debi ti goolu yin wa. E mu okan yin le, e ma so igbagbo yin nu.

Awon kan le maa wi pe odun ti fe e tan tabi ki won tile ni odun ti pari. Mo fi dayin loju wi pe ireti si wa wi pe owo yin si le ba ohun te n foju sun. E ma se je ki ohun to n sele ni ayika yin bu omi tutu si yin lokan. E ma se je ki ijakule dayin pada sile. E ma kari bonu, e ma so wi pe o ti pari. Ko ti i pari, ese bata kan pere loku fun yin lati debi ti e n lo.

Ohun to n sele lonii ko nihun se pelu ohun ti o sele lola. Awon nnkan ti ko seese fun yin lati nnkan bi osu mewaa seyin, le wa si imuse laaarin ojo mewaa sigba taa wa yii. Sugbon ti e ba so ireti nu, e ti so ohun gbogbo nu. Ti e ba ko lati tesiwaju, o daju wi pe e ko le debi ti goolu wa.

E le se amulo ogbon tuntun, e le paaro oju ona ti e n gba, sugbon e ri daju wi pe e ko pada sile. Awon Yoruba bo, won ni iku lonii, igbadun lola. Ohun to daju ni wi pe iku oni kii je ka jegbadun ola.

E ko lati ku sona bi eefin. E mu okan yin le bi jagunjagun. E dide nigba to ba n reyin, e sare nigba ti egun ba gun yin lese, e ma se gba ki ohunkohun fa yin seyin nitori wi pe ninu igbiyanju yin ni aseyori yin wa. E kaabo sinu osu tuntun, osu ayo, osu idunnu ati igbega.

Olayemi Olatilewa

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

martynov

Navy Stuff