Continue after the page break for English translation.
Kcee tú àsírí pé òhun ni olórin àkókò ní ìròlé èdè Nàìjíríà tí ó kókó lo okò bògìnì tí a mò sí Rolls-Royce phantom nínú fídío Orin rè.
Gbajúgbajà olórin, Kcee o ní ìràwò márùn-ùn. Nínú Orin tí ó ti se jé kí á rí àsírí rè gégé bí àsáájú tí ó kókó lo okò bògìnì “Rolls-Royce ní ilé-isé olórin ní orílè èdè Nàìjíríà. Òun ni ó jé òsèré àkókò tí ó kókó lo irú rè kan ní ibi fídío Orin rè, Shokori Bobo.
Àrídájú yí wá nígbà tí a fi òrò wa lénu wò ; ó so wípé; “Èmi ni òsèré àkókò ní orílè èdè Nàìjíríà láti lo Roll-Royce phantom nínú fídío Orin mi.
E lo wo Shokori Bobo. Ní àkókó yan ni èmi pèlú Phresh se fídío náà. Enikéni kò tí lo Roll-Royce nígbà yan. Ókéré nínú gbogbo èyí tí mo le rántí, òpòlopò ló ti ń wí tenu won nípa rè.Tí àwon kan so wípé D’banj ko Mr. Endowed Remix pèlú oko bògìnì yí nígbà tí ó wà pèlú Mo’Hits.
Kí l’erò, nítòótó? Tani àsáájú tí ó kókó lo okò bògìnì tí a mò sí Rolls-Royce ni ibi fídío Orin rè ní orílè èdè Nàìjíríà? Kcee tí ó gbé Orin rè Shokori Bobo jáde ní 2008 àbi D’banj nínú Orin rè Mr. Endowed remix ni 2011? Ó hàn gàdàgbà lóòtó? Sùgbón Ná.
Ejé kí á gba èrò yín nípa òrò náà…
Pages: 1 2