Home / Art / Àṣà Oòduà / Idi pataki meta ti ko fi ye ka maa fi ehin je eekanna
bitie

Idi pataki meta ti ko fi ye ka maa fi ehin je eekanna

1. Ehin le yingin tabi ki die kan lara ehin wa: Nigba mi-in ti a ba n gbiyanju lati fi ehin ge eekanna wa, ehin wa le lura won lojiji, eleyii si le fa ki ehin yingin legbe kan tabi ki die lara re kan danu.

2. Erigi enu wa ninu ewu: Bakan naa, fifi ehin je tabi ge eekanna wa le se akoba fun erigi. Okan ninu iriri awon dokita onitoju ehin fi ye wa wi pe nigba ti eniyan ba n gbiyanju lati fi ehin ge eekanna, oseese ki eekanna naa ha si aarin ehin, eleyii to le se akoba fun erigi enu wa.

3. O le fa aisan si ago ara wa: Awon idoti to wa ni abe eekanna, eleyii to kun fun kokoro aifojuri le sakoba nla fun ilera wa to ba se bee bo sinu enu wa.

Lakotan, Awujo wa tile ka asa ifehin ge eekanna gege bi iwa obun eleyii ti ko bojumu. E je ka yago fun iru iwa bee. E je ka wa obe sekele ti aa ma lo, eleyii ti enikeni ko ni ba wa pin lo, lati fi maa ge eekanna wa nigba gbogbo.

About admin

VI

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Ẹ Káàbọ̀ Beautiful Yoruba Words English Cannot Translate

Ẹ Káàbọ̀! (Step Into the Beautiful World of Yoruba Words That English Cannot Fully Translate)

TODAY’S LANGUAGE LESSONYoruba words and expressions that don’t have a perfect one-word English equivalentEnglish needs an entire sentence to explain these Yoruba words.You think you can interpret all Yoruba words to English directly with just one word? Okay.Tell me the interpretation of OMOLÚÀBÍSo what’s the closest English word you can think of?“Good person,” right? No“A person who is respectful, responsible, honest, hardworking, and well-raised” yesAnyways, let’s get into today’s lecture ÌwàLiteral translation: Character, behaviorBut “ìwà” is much deeper. It refers ...