Ìrọ̀rùn dé, Yínká Ayéfẹ́lẹ́ le è dúró kọrin báyìí
Ẹ̀dá tí tó bá sì wà lókè èèpẹ̀ tó ń ṣẹ̀mí, ìrètí kò pin fúnrúfẹ́ onítọ̀ùn, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí fún gbajúgbajà olórin jùjú n-nì, Yínká Ayéfẹ́lẹ́ bí ó ti jẹ́ pé ó ti le è nàró báyìí lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ tó bá wù ú.
Èyí kò ṣẹ̀yìn kẹ̀ẹ̀kẹ́ ìgbàlódé kan tó ní àwọn èròjà ìrọ̀rùn tó ṣe é yí sí ọ̀tún àti òsì, òkè àti ilẹ̀, ibi tó bá sì wu èèyàn, ló le è yí kẹ̀ẹ̀kẹ́ náà sí.
Yínká Ayéfẹ́lẹ́ , ló kéde pé ó ti rọrùn fún òun báyìí láti rìn pẹ̀lú kẹ̀ẹ̀kẹ́ tuntun náà lójú òpó Sítágíràmù rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì.
Ó fikún un pé ẹlẹ́yinjú àánú kan, tó pé orúkọ rẹ̀ ní Hon Obama Oludare Akande ló fún òun ní kẹ̀ẹ̀kẹ́ tuntun náà láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Ayéfẹ́lẹ́ ní “Mo lè dúró kọrin níbikíbi báyìí pẹ̀lú kẹ̀ẹ̀kẹ́ tuntun náà, ‘action’ bẹ̀rẹ̀ báyìí, mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Dáre Obama.”
Akọrin Tùǹgbá náà fikún un pé “ìrọ̀rùn dé bá mi gidi báyìí pẹ̀lú kẹ̀ẹ̀kẹ́ tuntun náà, Dáre Obama tún ti fún mi ní ìrètí láti rìn padà,.”
Ó wá gbàdúrà fún Aláànú náà pé kò ní mọ ìnira nílé ayé rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, ó ti lé ni ogún ọdún tí gbájúmọ́ akọrin ẹ̀mí náà ti pàdánù ọ̀pá ẹ̀yìn rẹ̀, tí kò sì leè rìn mọ́ nítorí ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé.
Fẹ́mi Akínṣọlá