Olayemi OlatilewaOkon Michael, eni aadota odun (50) to fi tipatipa fadi omobrin eni odun meji (2) ya perepere ni ipinle Akwa Ibom ti pada jewo fun awon olopaa wi pe awon aye lo wa nidi oro oun.
Michael, eni to je omo bibi ilu Mbak Ekpe to wa nijoba ibile Ibesikpo Asutan ni ipinle Akwa Ibom tun alaye re se fun awon oniroyin nigba ti ile ise olopaa ipinle naa se afihan won faye ri.
“Titi di akoko ti mo fi n ba yin soro yii, mi o tile le so ohun pato to mu mi se ohun ti won ni mo se. Oro mi ki n soju lasan o. E dakun, e ma foju lasan wo oro mi, o dabi eni wi awon aye n semi”.
“Ohun kan ti mo sakiyesi saaju asemase ti mo se ni bi enikan se riran si mi wi pe ogun nla kan mbe niwaju mi. Eleyii ti mo gbodo mura gidigidi ki ogun naa ma ba bori mi”, Micheal fikun oro re bee.
Micheal ati awon odaran afurasi meloo kan ti won se afihan won lori esun wi pe won ka ibon ati ogun oloro mo won lowo ni komisanna ipinle Akwa Ibom, Murtala Mani, se lalaye fun awon oniroyin wi pe laipe ni awon odaran afurasi naa yoo foju ba ile ejo fun idajo to peye labe ofin.
Gege bi akojopo iwadii ajo UN agbaye, eka to n risi idaran ati ogun oloro fi ye wa wi pe orileede South Africa ni iwa ibaje ifipabanilopo ti wopo julo ni ile Afirika.
Gege bi alaye ti ile ise olopaa orileede ilu Nelson Mandela se, won ni laaarin iseju-aya merindinlogoji (36 seconds) ni ifipabanilopo fi n waye kaariki orileede naa.