Home / Art / Àṣà Oòduà / Ogoji (40) eniyan n ja raburabu fun ipo gomina nipinle Ondo

Ogoji (40) eniyan n ja raburabu fun ipo gomina nipinle Ondo

Awon eniyan bi ogoji (40) lapapo ni won ti fi ife han bayii lati dije fun ipo gomina ipinle Ondo eleyii ti yoo waye ninu odun yii.

Ninu egbe oselu All Progressives Congress (APC), ogbon eniyan ni won ti nawo soke bayii lati dije ninu eto idibo abele egbe oselu naa. Ninu eto idibo yii gan-an ni won yoo ti ma mo taani yoo soju egbe onigbale lati dije ninu eto idibo fun ipo gomina ti yo waye ninu osu kewaa odun 2016.

Bakan naa, awon eniyan mewaa lati inu egbe osele Peoples Democratic Party (PDP) ni won ti n mura sile fun eto idibo abele egbe alaburada. Eleyii lo mu iye apapo gbogbo awon oludije naa je ogoji lapapo.

Awon oludije fun egbe PDP ni Komisanna fun eto idajo nipinle Ondo, Eyitayo Jegede, Komisanna fun eto ayika, Sola Ebiseni, Hon. Kingsley Kuku, Hon. Bakitta Bello ati Hon. Saka Lawal. Awon yoku ni Ogbeni Rotimi Jegede, Omooba Nekan Olateru-Olagbegi, Ogbeni Bamiduro Dada ati Hon. Gbenga Elegbeleye.

Awon oludije labe asia egbe APC ni Rotimi Akeredolu (SAN), Dr. Segun Abraham, Senato Ajayi Boroffice, Alhaji Jamiu Ekungba, Arabirin Jumoke Anifowose, Awodeyi Akinseyinwa Apata, Hon. Sule Akinsuyi, Olakunle Osunyikanmi, Odunayo Akinrinsola, Foluso Adefemi ati Bukola Adetula.

Awon yoku labe egbe oselu onigbale ni Dr. Bode Ayorinde, Olubunmi Agbaminoja, Oloye Segun Ojo, Sola Iji, Hon. Victor Olabimtan, Senato Tayo Alasoadura, Adegbonmire, Light Ariyomo, Paul Akinterinwa, Ayo Akinyelure, Olusola Oke, Ife Abegunde, Akinyinka Akinnola ati Dr.Tunji Abayomi.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Akeredolu

È̩yin òsìsé̩ mi nílò àyè̩wò coronavirus kíákíá- Akeredolu

È̩yin òsìsé̩ mi nílò àyè̩wò coronavirus kíákíá – Akeredolu Arakunrin Rotimi Akeredolu ti o je gomina ipinle Ondo lo n gba awon alabasise re niyanju ki won fi oro ti oun se arikogbon. O ni iba lasan ni o se oun ti oun si se itoju ara laarin ojo meji pere. O ni leyin re ni awon ore gba oun nimoran lati se ayewo ajakale arun coronavirus. Gomina naa ni “iyan jija lo n ba ore je” oun se ayewo ...