Gbajugbaja olorin fuji ti ina orin re si n jo lowo bayii ni o ti fa ibinu yo nigba ti won fesun kan an pe, o ni asepo pelu okan ninu awon olori Alaafin ti ilu Oya, Oba Lamide Adeyemi 111.
Wasiu ayinde ni lati igba ti oun ti di Mayegun ile Yoruba ni awon ota ti n gbogun, won n wa gbogbo ona lati ba oun loruko je, paapaa julo lodo eni to mu oun bi omo, iyen “Iku baba yeye” Alaafin Oyo.
O ni oun to je omo Yoruba gidi to mo ofin to si tun mo eewo. Kin ni oun fe wa de odo olori Badirat Ajoke? O ni pelu bi obinrin tile ti po to laye yii.
Wasiu Ayinde ni oun ko le fi oju oloore gungi.
K1 De Ultimate ni iwadii to gbopan ti n lo lowo lati fi oju asebi han. O ni oun si se ileri pe elese ko ni lo lai je iya nitori pe ile-ejo ni awon maa gba lo ti eni ibi naa si maa ko eri re jade.
Ogbeni Kunle Rasheed to je okan ninu awon alukoro Alhaji Wasiu Ayinde lo fi ise naa je faraye.