Home / Art / Àṣà Oòduà / Oniroyin Meji Ti Wa Ni Kirikiri Bayii: Ise Iroyin Won Lo Ko Ba Won

Oniroyin Meji Ti Wa Ni Kirikiri Bayii: Ise Iroyin Won Lo Ko Ba Won


Alase banki Fidelity ti Nigeria, Ogbeni Nnamdi Okonkwo ni Oniroyin Seun Oloketuyi gbe saye lori ikanni re, www.naijahottestgist.com wi pe oga banki naa feran ko maa se “yodiyodi” fun awon osisebirin banki re.

O ni yato si awon osisebirin re, awon kositoma ti won ba tun je “gala” oga banki, lila ni gbogbo won lodo Okonkwo, won ni maanu naa gbadun “kerewa” pupo ju.

Seun Oloketuyi ni awon olopaa koko gbe, eleyii ti won ti lo foju re bale ejo pelu esun ibanilorukoje eleyii ti oga agba banki Fidelity fi kan an.

Lori eleyii la wa, ni Ogbeni Dare Lasisi, Jagunmolu akoroyin ti n pidan lori ikanni darelasisi.co.uk tun kede wi pe won ti gbe Chris Kehinde Nwandu, olootu ikanni www.cknnigeria.com lori esun kan naa.

Gege bi ohun ti Dare Lasisi kede re, o ni awon oniroyin mejeeji naa ti wa ni Kirikiri bayii nibi won ti n fi kondo fun won lewa olomi sooro je laaro ati lale.

Sugbon ohun kan ti awon oniroyin ile Naijeria n wa okodoro re ni wi pe, se ooto ni iroyin ti Seun Oloketuyi ati Chris Kehinde Nwandu gbe jade abi won kan fi ba maanu naa loruko je lasan ni?

Se Ogbeni Nnamdi Okonkwo n gbe igbese yii lati fi aso bo iwa eeri ara re ni abi won paro mo lotito gege bi awijare agbejoro re, barisita Olakanmi Omisope.

Olayemi Oniroyin, e je n duro nibi ko to di wi pe won yoo ni ki n wa so eyi to ku l’Alagbon. Sebi e mo wi pe mi o laapon, ati wi pe mi o laiki ewa olomi sooro.

Sebi eyin mo mi…

 

Orisun: olayemioniroyin

About admin

VI

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Iwori meji

“Ohun Tó O Gbìn Lòó Kàá: Tomorrow Will Testify To The Good Or Evil You Do Today — The Powerful Revelation Of Ìwòrì Méjì!”

Looking at the Odù, Ìwòrì Méjì cast for today’s Ọ̀sẹ̀ Ifá, I can boldly declare that the wisdom in Ifá is second to none. It’s not surprising that it is the encyclopedia of Oòduà confederation. I have decided to give the message the title below.Ohun tó o gbìn lòó kàáWhat you sow you shall reap.Listen to the stanza from the Odù, Ìwòrì MéjìỌ̀pá ńlá ní ńyọ agogo idẹ lẹ́nuÒjò ńlá ní ńsọ òkítì di pẹ̀tẹ̀Ọ̀ṣun Ẹ̀wùjì ló fẹ́jẹ ló fẹ́muTí ...