Home / Art / Àṣà Oòduà / Won Ya Aso Iyi Saraki Niluu Ilorin Lojo Odun Ileya
saraki

Won Ya Aso Iyi Saraki Niluu Ilorin Lojo Odun Ileya


Okuta ati ogulutu ni awon eniyan bere si ni so lu aare ile igbimo asofin agba, Bukola Saraki, laaaro oni nibi to ti fe kirun yidi odun ileya niluu Ilorin Afonja.

Bi awon eniyan se n ju okuta bee naa ni won pariwo ole, ole, ole le omo baba oloye lori.

Kilode ti eni iyi di eni ete lojiji?

Gege bi Iwadii Olayemi Oniroyin, gomina ipinle naa, Abdulfatah Ahmed, ko sanwo osu fun awon osise ipinle Kwara eleyii to mu pupo awon musulumi ilu naa lati ma ri owo ra eran odun ati ounje fun awon omo ati aya ti won ko sile.

Afikun alaye won ni wi pe, owo iranwo ti ijoba apapo fi ran awon ipinle to je owo osu awon osise lowo, eleyii to je ti ipinle Kwara ni Bukola Saraki fi n jagun niluu Abuja lai wo ti igba ori ti ebi n pa niluu Ilorin.

Gbogbo awon eekan ilu bi Emir ilu Ilorin, Alh Ibrahim Sulu-Gambari ati awon oloselu nlanla lati ipinle kwara ti won jo koworin pelu Saraki ni awon eniyan so di eniyeye papo mo Saraki nigba ti yidi ti won ti fe kirun yipadi di rotiroti bi igba ti awon omo garaji ba da gobe sile.

Awon olopaa n yin tajutaju bee ni won yinbo soke; bajinatu si n dun keukeu kaakiri agbegbe yidi. Awon eniyan n sa soke sa sodo nigba ti awon kan ba awon oko to tele Saraki wa je.

Aimoye eniyan ti won wo jalamia funfun ni aso won ti di kampala nibi awon ero ti n tira won ti gbogbo re si di boo-lo-o-yago-lona ni yidi.

Olayemi Oniroyin ni oruko mi, awon omo Naija to wa ni orileede India ni won pe mi ni “Sultan”; Sultan Olayemi Oniroyin. Yeepa! Mo n wa owo lo lona mo gbayi. Lol.

Barka da Salah!

 

Source: olayemioniroyin

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Saraki

Saraki Tackles Buhari, Says Eighth Senate Organised Security Summit

Former President of the Senate, Dr. Bukola Saraki, yesterday faulted the claim by President Muhammadu Buhari that the Eighth Senate did not assist his administration to battle insecurity by organising a summit to generate ideas on what to do.Saraki’s media aide, Mr. Yusuph Olaniyonu, said in a statement yesterday that the immediate past president of the Senate, noted with dismay the claim contained in the seventh paragraph of a statement on Tuesday, by Buhari’s media adviser, Mr. Femi Adesina, that ...