Èèyàn ẹgbẹ̀rún kan àti irínwó dín mẹ́fà bá Kofi 19 rìn l’Amẹ́ríkà lópin ọ̀sẹ̀.
À fi kí á bẹ Ọlọ́run kó báwa dáwọ́ ibi dúró nílẹ̀ yìí àti lókèèrè to rí igbi gbogbo la lẹ́ni sí lórílẹ̀.
Gbogbo ìgbà ni àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kofi 19 ń pitú ọwọ́ rẹ̀ káàkiri àgbáyé o, bí ó se tun ti nawọ́jà rẹ̀ gbemi eeyan to pọ ni Amẹ́ríkà.
Ilẹ̀ Amẹ́ríkà tún ti ṣe àkọsílẹ̀ ikú ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan àti irínwó dín mẹ́fà látàrí àrùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì
Èyí sì ti mú àpapọ̀ ènìyàn tó ti kú di ẹgbẹ̀rún méjì dín láàádọ̀rún lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ati mẹ́sàn an (88,709)
Àjọ tó ń mójú tó ìgbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn ní Amẹ́ríkà (CDC) ló kéde èyí lọ́jọ́ Aìkú,
Wọ́n fi kún un pé mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó lé mẹ́tàdínláàdọ́rin àti márùn-únlélọ́gọ́ta ló ti ní àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ ọ̀hún. (1,467,065) èyí jẹ́ àfikún ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì sí díẹ̀ sí èyí tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀.
Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ní àkọsílẹ̀ àwọn tó kú jù nítorí àrùn Kofi 19 lágbàáyé.
Ṣáájú ni Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ rí Barack Obama ti ṣèkìlọ̀ lórí bí Ààrẹ Donald Trump se ń mú àrùn apinni léèmí náà Kòrónáfairọ̀ọ̀sì.
Fẹ́mi Akínṣọlá