Home / Art / Àṣà Oòduà / Enu Kofi Omo Ghana Pada Re Ba a Lese
mouth

Enu Kofi Omo Ghana Pada Re Ba a Lese


Eyin eniyan mi, ohun kan se pataki ti mo fe ko da wa loju; ti mo si fe ki oye re ye wa gidi.  Igbe aye eniyan wa ninu oro siso tabi ohun ti a fenu se ijewo re. Iru igbe aye ti eniyan yoo gbe ni i se pelu awon oro to n jade lati enu re. Eniyan si le ya aworan iru igbe aye to fe gbe nipa awon oro ti n jade ninu enu re.

Ti Yoruba ba ni “enu re ba eniyan lese.” Ohun ti won so ni wi pe enu ko ba eniyan. Sugbon bi a ba tu wo akanlo ede naa daada, a ri wi pe enu lo sokunfa ipo ti ese gbe eniyan de.  Aimoye awon eniyan ni won ti ko sinu wahala kan tabi ekeji nipase oro enu. Oro enu dabi obe oloju meji bi obe gambari ni. Bo se ran awon kan lowo bee lo n koba awon kan.

Ohunkohun to seese ko sele niise pelu orisi oro ti n jade lenu wa. Iru awon oro wo lo n jade lenu yin? Nitori oro enu yin ni ese yin ba sise. Oro te e fenu so, ni ese yin sise pelu. Ohun kan naa lo si n dari igbe aye eniyan. Ilu Ibadan ni mo ti se kekere, mo ranti okunrin ara Ghana kan ti n sise gbegilere leyinkule ile wa. Ti okunrin yii ko ba nise ti n se lowo tabi ti owo re ba dile, lara awon oro to maa n jade lenu re ni ‘ehin erin’.

A ni ti oun ba ri ehin erin, aye oun ti dara. Gbogbo igba ni i soro ehin erin; yala awada tabi igba ti o sawada. Ko le soro meji ko to menu ba ehin erin. Die lo ku ki awon ara ile wa maa pe ni “ehin erin” nigba naa. Emi o mo pataki ehin erin nigba naa, sugbon nipase Kofi ni mo fi mo wi pe ohun iyebiye bi igba eniyan ri ojulowo goolu ni ehin erin ni awon akoko yii.

Igba to ya ni Kofi ko kuro leyinkule ile wa nibi ti soobu re wa.(Inu soobu naa ni Kofi n su). Leyin to ti ko kuro ni ile wa nigba naa ni iroyin kan wa wi pe okunrin naa ti ri ehin erin ti n wa. Bakan naa la gbo wi pe o ti rin irin-ajo lo silu Oba. (O seese ko je wi pe ehin erin to ri lo mu ko kuro ni ile wa nigba naa).

Leyin bi osu mejo ti Kofi ti kuro nile wa, mo pade re lojo kan. Bi won ko tile yanu so fun eeyan, irisi Kofi fihan lotito wi pe ara oke okun ni.

Eniyan dudu ni, dudu re n dan, bee lo tutu bi ara omo tuntun jojolo. Kootu dudu lo wo pelu seeti funfun labe kootu. O rerin si mi, ehin re funfun bi yinyin. O fu mi lowo, o ni ki maa ki iya mi ti mo ba dele. Mo n wo akoyinsi Kofi lo, kootu re gbe tekiteki bee lo le mo o lara bi oga banki, o dan bee ni i ko yeriyeri.

Mo boju wo owo naira marun-un, eyo meji to ko le mi lowo, aganra ni; ontoosi bi asa Kamo. Mo fi imu gboorun owo naa, orisi turari ti n run lara Kofi ni i run lara owo naa. Abi maanu yii fi turari sowo ni? Mo sare ko sapo, mo si mori le ona ile. Igba ti mo ri Kofi Keyin re ni igbe aye mi. Ayafi ti maa ba tun foju kan lola. Igba kan ni won tile so wi pe okunrin naa ni oun ko ni pada si Naija mo. Ilu eebo ti dun mo gbaa.

Bi mo tile kere, sibesibe, mo mo iru igbe aye ti Kofi n gbe tele. Salubata oniroba ti won wo lo baluwe ni i wo kiri aye. Gbogbo igba ni ara re maa n bu to ba n sise lowo, se eranti wi pe gbegilere nise re? Kofi ana lo ti pada di eniyan pataki lonii ti n re oke okun bi eni lo Bariga. Dafiiidi so fun Golayaati omiran wi pe oun yoo ge ori re kuro lorun re. Bibeli so wi pe Dafiidi ko ni ida lowo ni akoko to n soro yii, sugbon oro to so pada wa si imuse.

Nje eyin tile ti se iwadii ohun ti obirin onisun eje so ko to kuro nile?

Ipo ti e wa lonii le buru jai, sugbon isoro ti e n la koja ko se pataki bi ohun ti e n fi enu yin so jade nipa igbesi aye yin. Kini awon ohun ti e n so nipa igbe aye yin ati ojo ola yin? Nitori oro enu yin yoo pada “re ba yin lese.” Ese yin ko si ni sai gbe yin debi ti oro enu yin so nipa re.

Olayemi Olatilewa ni oruko mi. Sultan Akoroyin to gbamuse ni won pe mi niluu India. Laipe, okiki mi ko ni pe kan kari aye. Bi won ka awon olowo aye, oruko mi ko ni gbeyin nibe laelae. Sebi ire ni mo yan, Eleda mi lo kobi.

E ku isimi oni!

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Why You Must Boycott any Infertile Hybrid or GMO Maize Products

Toxic U.S. Pestering Nigeria To Go GMO

Another day, another revelation about how the US will not let African nations determine their policies. A new investigative report reveals how activists against pesticides and GMOs in Nigeria are being smeared with the help of dollars stumped up by Washington – much to the delight of US agrochemical giants such as the health-scandal-embroiled Monsanto. Having been at the receiving end of a US State Department smear campaign ourselves, we can only relate too well to what the activists targeted ...