Home / Art / Àṣà Oòduà / Rose Odika setan lati se igbeyawo leyin iya-n-dagbe odun mewaa: Bobo kan lo jamo lowo niluu Eko
Rose Odika

Rose Odika setan lati se igbeyawo leyin iya-n-dagbe odun mewaa: Bobo kan lo jamo lowo niluu Eko


Leyin bi odun mewaa ti Rose Odika ti wa gege bi iya-n-dagbe, oserebirin omo Ipinle Delta naa ti setan lati ni oko tuntun.

Bi o tile je wi pe bonkele ni won fi oro naa se, ti won si n daso bo deeti ojo igbeyawo won mole. Sugbon iwadii Iwe Iroyin Owuro fidi re mule wi pe oseese ki iya Oyinkansola se igbeyawo pelu afesona ikoko re ki odun yii to kogba wole.

Rose Odika ko sai menu ba die lara idi ti igbeyawo re akoko fi di afiseyin teegun fiso. Awelewa oserebirin ti irawo re jade lodun 1993 nigba to se sinima Ododo Aye lati owo Olu Wemimo salaye wi pe ailafarada ati owu jije oun lo mu oun padanu igbeyawo akoko.

O ni gbogbo isele naa da lori aigbon ati ailoye lori oun nigba naa nitori omo odun mejidinlogbon (28) loun nigba igbeyawo akoko naa.

Nibayii ti Rose Odika ti le ni omo ogoji odun, igbagbo wa ni wi pe iriri ati ogbon ori re bayii yoo se opolopo iranlowo fun un ninu igbeyawo tuntun to fe tese bo naa.

Omokunrin onisowo kan niluu Eko ni Rose pada ja mo lowo. Iwe Iroyin Owuro si tun rigbo wi pe awon ololufe mejeeji yii ti n gbadun ara won ni koro fun ojo pipe ko to di wi pe won daba lati so yigi igbeyawo won papo.

Orisun

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti