Home / Art / Àṣà Oòduà / Ti o ba je wi pe emi ni Oliseh, ohun ti maa se ni wi pe…”- Adegboye Onigbinde

Ti o ba je wi pe emi ni Oliseh, ohun ti maa se ni wi pe…”- Adegboye Onigbinde

Vincent Enyeama ti n mu goli fun egbe agbaboolu Super Eagles ti dagbere fun egbe agbaboolu naa wi pe o digba kan na leyin odun metala to ti n sise sin ilu baba re.

Igbese ikede ifeyinti pajawiri Enyeama ko sadeede waye, ikunsinu kan lo waye laaarin oun ati akoni-moogba egbe naa, Sunday Oliseh.

Eleyii to mu oga re jarawo re loju gbogbo awon omo egbe naa nipa gbigba oye balogun egbe naa lowo re to si gbe fun Ahmed Musa.

Gege bi iwadii Olayemi Oniroyin, Enyeama pe de ipago igbaradi egbe naa to kale siluu Belgium nibi won ti n mura lati koju ifesewon oloresore ti n be niwaju won.

Enyeama to ye o de si ipago igbaradi lojo Aje sugbon to de be lojo Isegun salaye wi pe oun lo sin iya oun to rebi agba n re lo mo’un pe die, eniyan kii si niya meji laye.
Gbogbo alaye Enyeama dabi igba ti eniyan n yin agbado seyin igba lo jo loju Oliseh. O gba ipo balogun egbe naa taa mo si kapteeni lowo re o si gbe oye naa fun Ahmed Musa to je agbaboolu CSK Moscow.

Ohun to tun wa je papanbari ibe ni bi Oliseh se pase fun awon oluso alaabo ti won n be nitosi lati sin Enyeama jade nibi ipade naa.

Christian Chukwu, eni akoko ti o je balogun ati akoni-moogba egbe naa nigba kan seyin, salaye isele naa gege bi ojuti nla fun egbe agbaboolu Naijiria. O ni adari egbe naa ko fi ogbon agba yanju oro naa rara. O ni iroyin iru awon isele bee ki se ohun to ye ki eniyan maa gbo seti.

Adegboye Onigbinde, akoni-moogba to mu Enyeama wonu egbe naa lodun 2002, se alaye Enyeama gege bi enikan ti nnkan kii ba lara mu ni gbogbo igba.

Eleyii to maa n mu tapa si ofin ati ilana egbe naa. O ni eleyii si buu ku gege bi ipo re gege bi balogun.

Nipa ti Oliseh,

“bi o tile je wi pe Oliseh se ohun to to, sugbon ona to gbe gba buru jai.

“To ba je pe emi loun ni, mi o ni so ohunkohun ni akoko naa loju awon omo egbe yoku. Ti ojo ifesewonse ba ti de ni maa gbe oye naa fun elomii.

Leyin eyi, mi o si ni pe e mo fun awon ifesewonse ojo iwaju.

Oto ni ki eniyan mo ohun to ye ko so, oto tun ni ki eniyan mo idi to fi ye ko so iru oro bee jade ati ibi to ye ko ti so.

“Bi o se yeye Enyeama loju awon omo egbe yoku le fa irewesi okan fun awon omo egbe, eleyii to le se akoba fun ise tie gan-an.

“Lati ibere pepe, mi o fara mo bi won se yan Oliseh gege bi akoni-moogba egbe naa, nitori iriri re nipa imo isakoso kere pupo. Sugbon nigba to si ti de ipo naa bayii, dadan ni ki n gbero aseyori fun-un”.

Lara esun ti Enyeama tun fi kan oga re ni wi pe o fenu tabuku iya oun. Oliseh ni ohun to jina sooto gbaa ni wi pe oun bu iya to bi Enyeama to doloogbe. “Kini mo fe fi bibu oku orun se?”

Oliseh tun fi kun un wi pe oun to mu oun gbe igbese yiyo Enyeama loye ko ju lati mu awon egbe naa ji giri si ise ti nbe niwaju won.

Nibayii, ajo NFF ti pase fun awon egbe agbaboolu to ku lati bowo fun Oliseh to je akoni-moogba egbe agbaboolu Super Eagles. Won ni ilana ati ofin to ba si fi sile fun egbe naa labe ge, awon egbe pata si gbodo setan lati fi inu kan sise pelu re.

 

http://www.olayemioniroyin.com/

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

general

Army General Expose the Foreign Missions Behind Boko Haram And Bandits In Nigeria