Home / Art / Àṣà Oòduà / Won ti pago lori maanu to fowo kan oyan omoge

Won ti pago lori maanu to fowo kan oyan omoge

Arabirin, Ifeoma Okoroafor, eni odun mejidinlogbon (28), lo ti salaye fun ilejo Upper Area Court to wa niluu Abuja wi pe, Ogbeni Musa Goddy fowo gbe oun loyan jo ni oun se fo nigo lori.  Ogbeni Musa lo fejosun lago olopaa to wa ni Garki ni ojo kejidinlogbon (28) osu keji odun yii (28/02/2016) nigba ti Arabirin Ifeoma fi igo da iho si aarin ori re ti eje si bere si ni tu jade bi emu inu akeregbe.

“Sadeede ni arabirin yii fi igo da batani si gbogbo ori mi ati ara mi laise wi pe mo se ohunkohun fun un, kosi ohun to da emi a tie papo rara,” Ogbeni Musa se akosile alaye bayii fun awon olopaa.  Gege bi asoju ile ise olopaa, Urom Inah, se alaye niwaju adajo wi pe, iwadii awon ko fi eri kankan pataki han wi pe, lotito ni Musa fi owo gbe oyan Ifeoma ko to gun nigo.

 

Ninu awijare Ifeoma, eni ti n gbe ni agbegbe Dutse to wa ni Apo, “Oluwa mi, ti ko ba nidi, obirin ki i je Kumolu. Musa Goddy fowo gbemi loyan jo laise wi pe ife inu mi ni. Isele yii sele ni akoko ti mo duro nidiko lale, nigba ti mo n dari bo lenu ise oojo mi lati wo moto lo sile. Mo koju re wi pe kilofa katikati to n ba mi danwo. Ki n to mo ohun ti n sele, o ti bere si ni na mi to si fa aso mo mi lara. Ti ko ba se awon eniyan to wa nitosi ti won dasi, omokunrin naa ko ba seku pami lale ojo naa, ” Ifeoma se alaye bee niwaju adajo

 

Omobirin Ifeoma tun fi kun un niwaju adajo naa wi pe, oun ko jebi esun ti won fi kan oun rara.

Adajo agba, Alhaji Umar Kagarko, faramo idasile Ifeoma ti won ti gbeti mole pelu owo itanran egberun lona ogun naira (20, 000) ati oniduro to rese wale. Nigba ti won tun sun igbejo naa di ojo kesan-an osu karun-un odun yii (09/05/2016).

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

general

Army General Expose the Foreign Missions Behind Boko Haram And Bandits In Nigeria