Home / Art / Ọ̀RỌ̀ ÌSÍTÍ

Ọ̀RỌ̀ ÌSÍTÍ

Húùm…ètò ìsèlú tiwa-ntiwa
kò yẹkí ó mú ìjà wá bí ó bá se wípé l’òtítọ́ la
n’ìfẹ́ ará ìlú l’ọ́kàn, k’ára ó leè dẹ t’ẹrú-t’ọmọ
yàtọ̀ sí ìsèlú bí-o-ba-o-pá, bí-o-kò-báa-kó- bu-
bùú-l’ẹ́sẹ̀, èyí tó wọ́pọ̀ l’órílẹ̀ èdè wa!!. Àwa
ọmọ mẹ̀kúnnù t’àwọn Olósèlú ń kó Ìbọn, Ọ̀kọ̀
àti Àdá fún nít’orí à ti dé’pò sin ìlú, kò sàì mọ̀
wípé àwọn àti mọ̀lẹ́bí wọn ǹ bẹ n’ípamọ́, tí
wọn ń f’apá Ewúrẹ́ j’iyán, tí àwa ọmọ
mẹ̀kúnnù wá ń pa ara wa nít’orí ẹgbẹ̀rún kan
ni??!!.
Ẹ̀yin alárá wa, bí àsìkò ìdìbò lá ti yan àwọn
Olórí tuntun bá dé, ẹ jẹ́kí a la’jú wa s’ílẹ̀
dáadáa, kí àwọn Ọ̀jẹ̀lú ó máse tún dá wa
pada s’óko ìya tàbí ẹ kò rí bí ara se ń ni
gbogbo wa ni??. K’Édùmàrè máse pe ti wa
n’íyà l’órílẹ̀ èdè wa mọ́ o!!.

About Lolade

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

yoruba

Can we speak Yoruba language without code mixing? is it important?