Home / Art / Àṣà Oòduà / Itan fun awon omode: Kinihun ololaaju ati eku inu igbo
Kinihun ololaaju

Itan fun awon omode: Kinihun ololaaju ati eku inu igbo

Orisun
Kinihun ololaaju ati e ku inu igbo

itan

Itan ti a fe gbe yewo lonii ni itan Kinihun ololaaju ati eku inu igbo. Gbogbo wa la mo wi pe kinihun loba eranko. Oun naa si ni eranko to lagbara ju  lo ninu igbo nitori wi pe kosi eranko ti kinihun ko le pa je.

 

Lojo kan ni kinihun sun jeje re labe igi osan kan ninu igbo. Eku ba rin wa sibi ti kinihun sun si yii labe igi, o si bere si ni sere nibe. Eku n sere bee lo n sare yipo kinihun nibi to sun si.

Se e ri wi pe eku yii n fi iku sere. O ri dajudaju wi pe kinihun lo sun kale, sibesibe o n sere nibi ti kinihun sun si. Nibi ti o ti n sere ni kinihun ti taji. Bi kinihun se taji lo ya enu re to si n bu ramuramu. Kinihun sare sun mo eku, o ya enu re si i lati gbemi.

 

Sugbon eku ba sare dobale bee ni i be kinihun wi pe ko dakun.

Eku: “Kinihun oba eranko ninu igbo, joo, dari jin mi. Ma pa mi je. Mo mo wi pe mo ti koja aye mi lodo re. Gba mi nigba ojo ki n gba o nigba erun. Ti o ba le foju aanu wo mi lonii, ojokijo ti o ba niilo iranlowo mi, emi naa yoo ran o lowo.”

Kinihun wo eku wi pe iru iranlowo wo ni eku le se fun ohun. Sugbon nigba to ya, kinihun fi orijin eku. O si fi sile ki o maa lo ni ayo ati alaafia.

Lojo kan, ogboju ode kan ti oruko re n je Akinlade wo inu igbo wa. Se e mo wi pe awon ode ni oogun pupo. Akinlade mu kinihun laaye, o si so mo abe igi osan to maa sun si.  Akinlade fe fi ye awon ode to ku wi pe ogboju ode gidi ni oun se looto. O ni oun yoo koko lo pe awon ode to ku wi pe ki won wa wo kinihun ti oun fi owo lasan mu laaye ki oun to pa a.

Bi Akinlade se lo ke si awon ode to ku, ni eku tun gba idi igi osan naa koja. Nibe lo ti ri ti won so Kinihun mo igi. O sare sun mo o, o si beere ohun to sele. Kinihun ko ejo, lo ba ro fun un pata. O ni ode ti lo pe awon ode to ku wa, o ni ti ode ba de ni won yoo to yin oun ni bajinatu. Igba ti eku gbo eleyii lo ba bere si ni fi ehin tu okun ti ode fi so kinihun. Eku ni bu-fun-mi-n-bu-fun-o ni opolo n ke lodo. O ti ran mi lowo ri, dandan ni ki emi naa o ran o lowo.

Alaye akanlo ede ati awon oro to se koko

Ololaaju: Ololaaju tunmo si olola inu iju. Iju ni won tun n pe ni igbo. Kinihun je eranko to lola ju lo ninu igbo. Oun kan naa si ni oba eranko patapata.

Ramuramu: Orisiirsii eranko ni won ni bi won se n dun. Yoruba maa n lo ramuramu fun didun kinihun ninu igbo.

 

Gba mi nigba ojo ki n gba o nigba erun.” Tun mo si wi pe ki eniyan se iranlowo fun wa nigba isoro ki awa naa le se iranlowo fun eni naa pada nigba ti isoro ti e naa ba de.

Ogboju ode.” Tunmo si akinkanju ode tabi ode alagbara

Bajinatu” je ibon ibile eleyii ti awon ode fi n peran ninu igbo.

“Bu-fun-mi-n-bu-fun-o ni opolo n ke lodo.” Itunmo owe yii ko yato si “Gba mi nigba ojo ki n gba o nigba erun” eleyii ti a se alaye re saaju.

Ogbon wo ni itan yii ko wa? E fi esi ranse si nomba isale yii pelu oruko yin ati oruko ile iwe yin ati ilu ti e n gbe.

 

Orisun

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

orisa

The World of the Yoruba Orisa