Opolopo ni i pokiki Olajumoke Orisaguna omo oniburedi gege bi oloriire ti Edumare da lola ojiji pelu bo se se alabapada agbaoje ayaworan ati olorin ti n je TY Bello. Laaarin iseju kan, omo oniburedi di orekelewa oba onise oge. Aimoye awon ile ise alaso oge ni won ti bere si sanwo tabua fun un latari igbelaruge ati ipolowo ti n se fun awon oja won. Okan ninu awon banki igbalode tile ti yan gege bi asoju won eleyii ti aimoye naira si ti sokale si i lapo. Aimoye awon eniyan ni won gbadura ki won ba iru aanu ati ore ofe bee pade.
Sugbon kini kan se pataki ti o ye ka fi kogbon, buredi lo so aye Olajumoke di iyanu. Enikan so fun mi ni awon akoko kan seyin wi pe, ijakule elomii bere nikete to kawe gboye nile iwe giga. Nitori wi pe sabuke to gba ti bo o loju.
Iwe eri ni i gbe kiri, o si ko lati mu ise kankan se yato si ise ti sabuke re le fi le e lowo. Aimoye awon eniyan ni i wase lode toni, ki i se wi pe kosise, iru ise ti won wa ni ko wopo. Sugbon ni awon akoko kan ninu igbe aye eda, a ni lati gbe igberaga ti sibi kan, ki aye le dun gbe fun wa. Ohunkohun ti a ba ri lati fi pawoda, e je ka gbiyanju lati mu sa loogun titi ti igbega wa yoo fi de. Meloo ninu awon odo asiko yii ni won setan lati lo kose owo leyin ti won jade ileewe?
E ma je ki ise kankan ti wa loju lati se niwon igba to ba ti je ise to gunle otito. Eniyan le ma sise asobode lonii, eleyii ko yi kadara re pada tabi iru eni ti Edua oke so wi pe yoo je laye. Eniyan le se alagbafo debi ti ogo re wa. Ti a ba n gbadura wi pe ki Oluwa bukun wa, ki i se nipa jijoko sile lai se ohunkohun. Ti e ko ba nise lowo, mo ro yin ki wa ise kan se.
O le je ise kekere, sugbon ninu igbinyanju yin ni Edua o ti saanu fun yin. Koda, eniyan le sise ofe tori ko ma ba joko sile lasan. Ti Jumoke ko ba ta buredi ko le de ibi to de lonii. Ti eniyan ko ba ri ohun to fe, a ma fe ohun to ba ri nigba mii. Kadara eda wa lowo Eledumare oba ogo. Oosa oke nikan lo si mo ona teda o gba soriire laye.
E ma so ireti yin nu ninu Naijiria. E fi ireti sinu ogo ati ola re. O daju wi pe leyin okunkun, imole n bo dandan ni. E ku ikale!
http://www.olayemioniroyin.com/2016/02/olajumoke-omo-oniburedi.html
Omo oni buredi. Mo gbadun e daku. O lenu pa
is say wetin ? Omo yii ni oko o. E le gbadun re bi buredi amo o ti loko ati omo.
Ola ti jumoke bayii.. Ki a ma ke ola Na loku