Home / Art / Àṣà Oòduà / A kú àmójúbà *Osù Agemo (July)

A kú àmójúbà *Osù Agemo (July)

Bí a se wonú osù yìí, a kò níí se gégé ibi, ibi kò níí se gégé wa. Ikú iwájú tó ñ pa wón, odò èyìn tó ñ gbé won ón lo, Oba Adédàá kò níí ka ìpín òkóòkan wa mó irú re. Ní ojó tí ebi bá ñ pa ilé, a kò níí sí nílé, béè ni a kò ní rìn lónà ní ojó tí ebi bá n pa ònà. A kò níí se déédé ìjàmbá bí ó tilè wù kó kéré mo, ògiri àlàpà kò níí wó lù wá mólè, béè ni a kò níí rí ìjà iná.
Òrò orílè-èdè Nàìjíríà di owó Èdùmàrè. Kí báábá ibi tó ñ be ní iwájú lo rè é bo igi oko nínú igbó, kí bààbà ibi tó ñ bò léyìn lo rè é borí èrùwà sùsù nínú òdàn. Ibi gbogbo kó máa gbe inú ìgbé wo wá, ire gbogbo kó máa yalé wa.

_Mó tòní bàjé_
_Énìyàn ní ñ se é_
_A dífá fún Òrúnmìlà_
_Ikú ñ kan ilé Èdú yún_
_Àrùn ñ kan ilé Èdú rè_
_Gbogbo ibi ñ kan ilé Baba ní lílo_
_Ebo ni Awó ní kó se_
_Ikú mó yá a lo_
_Àrùn mó yá a lo_
_Òfò mó yá a lo_
_Òràn mó yá a lo_
_Ejó mó yá a lo_
_Ìjà mó yá a lo_
_Èse mó yá a lo_
_Àkóbá mó yá a lo_
_Àdábá mó yá a lo_
_Àseèrí mó yá a lo_
_Ègbà mó yá a lo_
_Gbogbo ajogun Ibi kí e mó yá a lo_
_Ìgbín kò mà nílé Olojò ó wò_
_A ti kìlò pé kí e má wo ilè yìí mó_
_Inú igbó ni omo Esì ñ sùn_
_Inú igbó ni Kóñdó gbé so_
_A ti kìlò pé kí e má wo ilè yìí mó_

Ààbò àti ìsó Olódùmarè tó péye yóò wà lorí gbogbo wa.

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

masoyinbo15102024

#Masoyinbo Episode Sixty-Five: Exciting Game Show Teaching Yoruba language and Culture.