Ààrẹ Buhari kí àwọn ọmọ Nàìjíríà kú àfaradà bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ lásìkò Coronavirus yìí
Nínú ọ̀rọ̀ ìkínni kú ọdún Àjíǹde tó fi ṣọwọ́ sáwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ààrẹ Buhari ṣàlàyé pé ìgbáyégbádùn àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kìí ṣé oun tó ṣe é dúnàádúrà lé lórí ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ ààbò àti àlàáfíà aráàlú ṣe kókó.
Ààrẹ fi kún un pé, ó wu òun kí wọ́n jáde ṣọdún Àjíǹde, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Covid 19 yìí ń gbẹ́mìí kúkúrú gígùn, o sì jẹ́ ohun ìbànújẹ́.
Ààrẹ wá fikún un pé,ki àwọn ènìyàn o tẹ̀lé òfin kónílé-ó-gbélé tí Ìjọba ti pàṣẹ kónílé-ó-gbélé o.
Àdúrà làsìkò yí gbà pẹ̀lú ìfaradà láti ṣẹ́gun àrùn apinni léèmí Coronavirus–Ààrẹ Buhari
Fẹ́mi Akínṣọlá