Gégé bí a ti mò wípé ilé-ifè jé ìlú tí ilé-èkó gíga wà, tí ó sì kún fún àwon akékòó bíi àwon akékòó ilé-èkó gíga ifáfitì ti Obafemi Awolowo university (OAU) àti ilé-èkó gíga ifáfitì ti Oduduwa university ilé-ifè (OUI).
Yorùbá bò wón ní àgbàrá òjò kò ní òhun kò n’ílé wó sebí onílé ni kò ní gbà fun, àgbàrá òjò eléyìí ti w’olé nítorí àwon ará ilé ti gbaa láyè tí ó pò.
E má jé kí á k’ólé s’ójú àgbàrá mó a kò a ò gbó, kí á má dalè sí ojú àgbàrá mo, a kò a ò gbà. Erù àwon akékòó tó sòfò ló pò, ìwé èrí àwon míràn tilè ti bómi lo .
Kí elédùmarè sàánú wa , kí ó má jé kí á ríjà omi.