Don't Miss
Home / Art / Àṣà Oòduà / Aja To Rele Ekun To Bo..
asa yoruba

Aja To Rele Ekun To Bo..

Aja ti o ba rele ekun ti o si pada lai f’arapa ti iru aja be o si le gbegba ope olowo aja be ni yoo fi se ounje ajesun laipe ojo.
KABIYESI ILU MOYE ni a o ba maa pe ni aja ti o rele ekun to bo. Ki oro temi maa ba dabi t’aja ti olowo re yoo fi se ounje ajesun ni mo se gbegba ope.
Mo dupe lowo OLODUMARE oba mi ti o je wipe KIKI ENI TI WON PAMO NIKAN NI O YO NINU EWU. Mo dupe fun ipamo yin, abo yin, iso yin, aduroti yin ati mimu ileri yin se lori mi, Eledua mo dupe o.
Ti mo ba legberun ahon ko to lati dupe ore, tori bi mo ni egbegberun bilionu ko le ra abo iseju kan fun mi. Ti nko ba ni paro kii se mimoose mi, kii se ibon owo mi, kii se ijooloto mi, kii se adura mi bikose ANU TI MO RI GBA. Tori na ni mo se wipe OLODUMARE E SEUN O, TITI AYE NI N O MAA GBE YIN GA.
Mo dupe lowo gbogbo ebi, ara, ore ati ojulumo pata ti e nfi adura ran mi lowo losan lori, Eledua ko ni doju adura ti enikookan wa o.
Mo nfi akoko yi so fun yin wipe emi omo yin, aburo yin, egbon yin, boda yin, oko yin, ore yin, ti e nfi adura ranse si loke oya lati bi odun meji seyin ti pada sile layo ati alafia, se e ri wipe TEMITOPE bayi.
Haaaa eyin ilu Moye, e ma ma dami daa ke, e si n wo mi niran, e o si dakun dabo ba mi dupe ki e ba mi yin Olodumare oba mi ti o pabida sobidire fun mi.
OLODUMARE ABO MI, E SEUN SEUN OOOO.

 

Cc-Abel Simeon Oluwafemi

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti