Òrìsà ni olókun jé, a gbó wípé òun ni ó bí ajé, ó tún jé òrìsà orò àti ti ìsàlè òkun. Olókun ni ó n darí omi ó sì ní àse l’órí gbogbo ìsèdá inú omi . Olókun máa n fún ni ní orò , èmí gígùn abbl. Ajé olókun mo bè ó kí o wá fi ilé mi se ibùgbé (Àse).
Iba Olodumare. Iba Akoda Aye, Iba Aseda Aye, Iba Eniyan. Ekaro, eku ojumon. Ojumon ire gbogbo. Loni, Olodumare yoo silekun gbogbo ire fun o yoo si ti ilekun ibanuje, ekun, ipayin keke pa. Lori jije ati mimun re loni, ooni gbe omi p’ari, oosi niigbe ata pari gbona orun lo pelu. Ina ola re konii joku rebete. Ooni fo loju, ooni ro lapa ro lese. Gbogbo ire ti o ti wo agbole re, koni pada baje. Ooni fi eda re ...