Home / Art / Àṣà Oòduà / Akékòó Odún Keta (300l) Ti Oau Ti Eka Èkó ‘Pharmacy’ Rì Sómi, Tí Ó Sì Kú Sí Odò-ìwè (Swimming Pool) Ní Hòtéèlì. 
okunrin

Akékòó Odún Keta (300l) Ti Oau Ti Eka Èkó ‘Pharmacy’ Rì Sómi, Tí Ó Sì Kú Sí Odò-ìwè (Swimming Pool) Ní Hòtéèlì. 

Akékòó odún keta (300l) ti eka èkó pharmacy, Obafemi Awolowo University; pàdánù èmí rè Lánàá léyìn ìgbà tí ó rì sómi nínú odò-ìwè (swimming pool) ní hòtéèlì tí a mò sí Hilton.

A mò ó sí Fatile Emmanuel. Ìsèlè yí selè nígbà tí Emmanuel lo sí hòtéèlì láti lo lúwèé pèlú àwon Òré rè méji.

Orísun tí a ti ríi gbó sopé olóògbé náà rì sínú odò-ìwé , látàrí wípé kò tètè rí jákèètì ìdábòbò (life jacket) nígbà tí Ìsèlè náà sè.

 

Baba Faros, alukoro Pharmaceutical Association of Nigeria Students ni a rí I tí ó so pé; “mo gba ìpè ní nkan bi agogo mérin àbò (4:30pm) Lánàá láti òdò òmòwé kan tí orúko rè ń jé Akinwale (Dr. Akinwale) wípé àwon nílò ìrànlówó mi ní kíákíá ní ilé-ìwòsàn ilé-èkó yìí. OAUTH, nígbà tí mo débè agbà mi ní ìmòràn láti fi ìdí rè múlè wípé ó ti kú tàbí kí á gbé kúrò kí èmí rè tó já tán; a kúrò ní ilé-ìwòsàn ní nkan bí agogo méwàá àbò (10:30pm)ní alé ojó náà “,ó so béè.

 

Ní inú ìgbà yí. À so fún akoròyìn wípé àwon olóòpá láti Moore ti lo mú òsìsé tí ó wà nípa jákèètì ìdábòbò ní hòtéèlì náà àti àwon akékòó OAU méjì tí won dìjo lo lúwèé ní hòtéèlì pèlú oloogbe.
Lówólówó yìí, a wà ní Moore ní ilé-isé olóòpá gíga láti gba àwon akékòó méji náà kalè. À ń gbó àwon òrò èyìn díèdíè wípé àwon olóòpá ti kéde ejó náà gégé bi èsùn apanìyàn. Ìgbìmò náà tí bèrè lóòní; Orísun sí…..

Continue after the page break for English version

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti