Home / Art / Àṣà Oòduà / Àlùfá tọ́ bá ọmọ ọdún méje sùn, wẹ̀wọ̀n ọdún Márùn- ún ní ìpínlẹ̀ Ekiti
alufa

Àlùfá tọ́ bá ọmọ ọdún méje sùn, wẹ̀wọ̀n ọdún Márùn- ún ní ìpínlẹ̀ Ekiti

Ọjọ́ gbogbo n t’olè, ọjọ́ kan n t’olóhun.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti tífìtàn balẹ̀ bí wọ́n ṣe jẹ́ ìpínlẹ̀ àkọ́kọ́ tí yóò bẹ̀rẹ̀ láti máa dárúkọ ọ̀daràn afipá bánilòpọ̀ hàn àti láti máa dójú tì wọ́n.

Gómìnà ìpínlẹ̀ náà Kayode Fayemi gbé e jáde lójú òpó twitter rẹ̀ pé àsìkò ti tó láti máa fi ojú aṣebi hàn lásìkò tó gbé àwòrán ẹni ọ̀wọ̀ Asateru Gabriel ti ìjọ St Andrew Anglican Ifinsin -Ekiti nígbà kan.

Gabriel ti fọjú ba ilé ẹjọ ó si jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan, nítori ìdí èyí yóò maa ṣẹ̀wọ̀n ọdún márùn ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Ìjọba ní Ado Ekiti fún ẹ̀sùn ìfipá bá ọmọ ọdún méje lòpọ̀.

Ní bayiì orúkọ rẹ̀ ti wọ ìwé àkọsílẹ̀ àwọn olùfipábánilòpọ̀ ní ilé ìṣẹ́ ìdajọ́.

Èyí jẹ́ ìpínlẹ̀ Gúúsù- ìwọ̀ -oòrùn àkọ́kọ́ tí yóò gbé ìgbesẹ̀ yìí.

Fẹ́mi Akínṣọlá
Iroyinowuro

About ayangalu

VI

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

amoke

Itan Omooba Amoke

Omooba obinrin kan gbe ni ilu alayo, orewa pupo ju oruko re si nje Amoke ni ile Yoruba atijo. Orewa pupo debi pe gbogbo okunrin ilualayo niwon ko enu ife si, koda awon okunrin ilu agbegbe won gan o gbeyin. Amoke n ma bu gbogbo awon okunrin ti oba soro ife leti re koda atun pariwo lewon lori. Oro yin kan Oba ilu ti oje baba re lomi nu. Loru ojo kan, Oba ji Amoke sile o de ba so ...