Ẹ̀ṣọ́ ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) ‘Àmọ̀tẹ́kùn’ ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ káàkiri ilẹ̀ káàárọ̀ o ò jíire.
Ọ̀rọ̀ ti di olójú ò níí yajú ẹ̀ sílẹ̀ kí tàlùbọ̀ ó yíwọ̀ọ́ àti pé ọmọ onílùú kò níí fẹ́ ó tú lọ̀rọ̀ dà báyìí ó, bí.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, Kayode Fayemi ti kéde pé gbogbo ètò ti tò báyìí fún Ilé iṣẹ́ ètò ààbò ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) ”Àmọ̀tẹ́kùn”” láti bẹ̀rẹ̀.
Fayemi ní ọjọ́ kẹsàn án, oṣù kínní, ọdún 2020 ni ètò náà táwọn gómìnà mẹ́fà apá gúúsù orílẹ̀-èdè- Nàìjíríà ìwọ̀ oòrùn ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ yóó bẹ̀rẹ̀ káàkiri ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá).
Gómìnà Fayemi fi ọ̀rọ̀ ọ̀hún léde nínú ọ̀rọ̀ ọdún tuntun tó báwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Èkìtì sọ L’ọ́jọ́rù, ọjọ́ kínní, oṣù kínní, ọdún 2020.
Fayemi ṣàlàyé pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ‘Àmọ̀tẹ́kùn”’ yóó máa ṣe ìrànwọ́ fún àwọn agbófinró ní gbogbo ìpínlẹ̀ mẹ́fà nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá).
Gómìnà Èkìtì ní Ìjọba ti setán láti ríi pé ètò ààbò gbópọn síi nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá).
Ó ní lóòtọ́ọ́ ni pé ìwà ọ̀daràn kò le tán nílẹ̀ pátápátá, à mọ́ àwọn gómìnà mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ti fẹnu kò láti ríi pé ìwà ọ̀daràn dínkù káàkiri ilẹ̀ káàárọ̀ o jíire.
Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ OPC àtàwọn ẹgbẹ́ ajìjàgbara míì nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá) ti ké pe àwọn gómìnà yìí tẹ́lẹ̀ pé kí wọ́n fáwọn láṣẹ láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn agbófinró láti gbógun ti àwọn jàǹdùkú tó ń dá rògbòdìyàn sílẹ̀ nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá).
Fẹ́mi Akínṣọlá
?South-West Nigeria?? launch security outfit 'Amọtẹkun' (The Leopard). pic.twitter.com/IJEebfZ4Oi
— Kayode Ogundamisi (@ogundamisi) January 3, 2020