Àmọ̀tẹkùn ni wọn yóó maa pe orúkọ ikọ̀ tó n pèsè ààbò yíká ilẹ̀ Yorùbá…..Akerdolu
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣe Yoruba bọ ,wọn ni Ogun ti yoo wọle koni,ọna la a tii pade ẹ lo bi ọrọ ti Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu sọ,bi o ṣe kede pe Amotẹkun ni wọn yoo maa pe orukọ ikọ to n pese aabo yika ilẹ Yoruba.
Bẹẹ ba gbagbe, lọjọbọ ni ipade eto aabo tun waye lati wa ojutu si awọn ipenija aabo to mẹhẹ to n ba ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria naa finra.
Awọn gomina ati ileesẹ ọlọpaa si ti se agbekalẹ igbimọ alaabo kan ninu eyi taa ti ri awọn osisẹ agbofinro ati awọn ọmọ ẹgbẹ akọya fun ilẹ Yoruba, OPC, awọn ọdẹ ibilẹ ati awọn asọgbo.
“Àsìkò yí ló yẹ kí Yorùbá fi ìmọ̀ ṣọ̀kan”
Ni itẹsiwaju abọ ipade naa, gomina Akeredolu ti gbe ọkọ nla Hilux bii ogun ati ọkada ọgọfa kalẹ fun ikọ Amọtẹkun naa, eyi ti yoo wagbo dẹkun fun awọn eeyan to n pagidina eto aabo lẹkun Kaarọ Oojire.
Lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ, Kọmisana feto iroyin ati itaniji nipinlẹ Ondo, Donald Ojogo, salaye pe lati
igbadegba ni igbogun ti eto aabo to mẹhẹ yoo maa waye, eyi ti awọn gomina n se atilẹyin fun.
Ojogo ni gbogbo awọn ọdaran to n fi igbo boju lawọn yoo fin jade bii okete, ti wọn yoo si sa kuro tefetefe jinna sawọn
ilu to wa nilẹ Yoruba.
O wa fọwọ gbaya pe laipẹ ni wọn yoo si asọ loju eegun ikọ Amọtẹkun naa, ti wọn yoo si kawọ ikọlu awọn ọdaran to n waye nilẹ Kaarọ Oojire duro.