Home / Art / Àṣà Oòduà / Àríwá Nàìjíríà, Ẹ Sọ Ẹran Jọ̀bọ̀jọ̀bọ̀ Nù Bí Ẹ Ṣe Yọ Sanusi – Soyinka
wole soyinka

Àríwá Nàìjíríà, Ẹ Sọ Ẹran Jọ̀bọ̀jọ̀bọ̀ Nù Bí Ẹ Ṣe Yọ Sanusi – Soyinka

Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Soyinka ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí Ìjọba ìpínlẹ̀ Kano, lábẹ́ ìsàkóso Gómìnà Abdullahi Umar Ganduje, lórí bó ṣe rọ Lamido Sanusi lóyè, gẹ́gẹ́ bí Emir ìlú Kano.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nínú àtẹ̀jáde kan, Soyinka ní ìyọnípò Sanusi túmọ̀ sí pé, àwọn ará Àríwá Nàìjíríà kò tíì setán, láti gba òtítọ́ àti àṣà ìgbàlódé láàyè.

Soyinka ní ó ṣeni láànú pé Gómìnà Ganduje kò ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi tó le gbà á sílẹ̀ ọwọ ara rẹ ló ti ń mú ìdájọ́, àti pé, Sanusi tí wọ́n rọ̀ lóyè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn tó leè mú àyípadà ńlá bá àwọn ará Òkè Ọya.

Ẹ̀wẹ̀, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kaduna, Nasir El-Rufai àti Emir tẹ́lẹ̀, Muhammadu Sanusi ti múrìn Abuja pọn, kúrò ní Awe.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna ló fi léde bẹ́ẹ̀ lójú òpó Twitter wọn pé àwọn méjéèjì ti kúrò ní Awe báyìí lọ sí ìlú Abuja.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

wole soyinka

Nigerians number one problem is religion —Says Prof. Wole Soyinka

Nigerian author and Nobel laureate, Wole Soyinka has revealed why he believes religion is the number one problem of Nigerians. According to him while speaking with a professor of African Literature, Dr. Louisa Egbunike, religion has become an excuse for citizens to flout the laws and behave irrationally. Soyinka further stated that in Nigeria, religion is used to subvert the rights of others, to the extent of primordial rights, to kll, not just singling, but collectively, to brb down the ...