Home / Art / Àṣà Oòduà / “Awon soja yin mi ni bajinatu, won fe pami” – Olu Falae
olu falae

“Awon soja yin mi ni bajinatu, won fe pami” – Olu Falae

*Awon ika eniyan wo lo wa nidi isele yii?
*Se agbanipa ni won tabi awon soja ti won se palapala nigboro?

Oloye Olu Falae ni ori ti koyo bayii lowo iku ojiji nigba ti awon soja kan ti enikeni ko mo orisun won sadeede doju ibon ko moto re loju ona Akure si Ilesa.

Baba yii lagbo wi pe o n rin irinajo lo si Ile-Ife lojo Isegun to koja yii nibi ipade awon Afenifere pelu Ooni tuntun, Oba Adeyeye Ogunwusi.

“Igba wo ni awon ajinigbe si ji mi gbe na, nibayii, won tile n lepa lati pami ni.” Olu Falae se alaye fun awon oniroyin. “Akure ni mo ti n bo, nigba to ku die ta ma de Ilesa, a ri oko kan niwaju wa. Oko nla van kan naa si tun wa niwaju tie, niwaju loun. Oko to wa niwaju wa n gbiyanju lati sare ya oko van to wa niwaju lo un sile, bee gele ni awa naa ba tele. A ti fe koja won ni mo gbo tako-tako iro ibon lara oko mi.

Oko van yii ko duro, o tun tena lo ni. Igba ti a de Erin-Ijesa la salaye ohun to sele fun awon olopaa ta a ri nibe wi pe, oko van nla kan tabon luwa ni ikorita Ile-Oluji”. Oloye Olu Falae tun n se alaye re siwaju pelu edun okan nla nipa awon isele ti n sele si i.

“Mi o modi ti won fi jimi gbe titi di akoko yii, mi o modi ti won fi fi olopaa gbemi lodun 1997 ti won si timi mole fun odun meji gbako. Nibayii, won tile fe pami patapata ni,” Falae se alaye re bee pelu edun okan nla.

Sugbon sa, iwadii ko ti fidi re mule boya awon agbanipa ni awon soja to yinbon tabi awon soja oniwa palapala ti won fibon dabira to wu won. Ju gbogbo re lo, iwadii awon olopaa si n tesiwaju lori isele naa.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

olu falae

I Earned No Salary As Minister, Says Olu Falae

  A previous Secretary to the Government of the federation, Olu Falae, on Wednesday, reviewed some of his encounters in the hands of his captors, who requested N100million as payoff in the wake of grabbing him from his farm in Akure in September. Mr. Falae, who talked when he got a previous Kano State representative, Ibrahim Shekarau, in his living arrangement in Obaile, said when he told the criminals he had no cash, they were angry, indicating out that he ...