Aye̩ye̩ o̩jó̩ò̩bí Sikiru Lemon
Bí a bá dájó̩, o̩jó̩, á pé, bí a dósù, osù á kò. Gbogbo o̩jó̩ ko̩kàndínló̩gbò̩n, osù ké̩rin o̩dún ni o̩jó̩ò̩bí Alhaji Sikiru Lemon.
Yorùbá bò̩,wó̩n ní “àìbá wo̩n sí níbè̩ ni àìbá wo̩n dá síi”. Ìwé ÌRÒYÌN ÒWÚRÒ darapò̩ mó̩ àwo̩n e̩bí, ò̩ré̩, ojúlùmò̩ àti olólùfé̩ láti sàjo̩yò̩ o̩jó̩ òní pè̩lú ò̩ré̩ wa Sikiru Lemon.
Àkàlàmò̩gbò kò ní saláì le̩gbè̩rún o̩dún láyé. È̩mí re̩ á se ò̩pò̩lo̩pò̩ o̩dún lókè eèpè̩ nínú o̩lá, iyì, è̩ye̩ àti aláfíà pè̩lú gbogbo olólùfé̩.
Igba o̩dún, o̩dún kan
Ọmọ Oòduà Naija Gist | News From Nigeria | Entertainment gist Nigeria|Networking|News.. Visit for Nigeria breaking news , Nigerian Movies , Naija music , Jobs In Nigeria , Naija News , Nollywood, Gist and more

