Home / Art / Àṣà Oòduà / Eeto Owe L’esin Oro
Yoruba Festival

Eeto Owe L’esin Oro

A ku deede asiko yii o gbogbo olugbe aafin ilumoye, eeto yin eeto wa owe l’esin oro ni o tun wole de weere yi ooo, e wa nkan fidile ki a dijo gbadun eeto ti toni. Siwaju ki eeto o to bere, mo dupe lowo Eledumare oba aseda ti o je ki a dagbere fun eeto ni ose ti o lo, ti a si tun ni anfaani lati tun pade ni ose yii, Oluwaseun, Olodumare maa je ki enu ope wa o kan ooo.
Mo ki kabiyesi olumoye akoko, moki yeye oba, awon olori laafin, awon ijoye oba, gbogbo igbimon aafin ati awon omo’ba l’okunrin ati l’obinrin.

Eeto Owe L’esin Oro 1
Nje a tun ti de bi a se maa n de gegebi ise wa ni gbogbo ojo mejo, lori eeto yii ni a o ti maa yannnana awon owe ile wa lolokanojokan ti a o si maa ko arawa ni itumo ati lilo awon owe bee. Ni bayii, e je ki a bosi agbami eeto naa.
Owe akoko ti a o maa gbeyewo loni loo bayii: O D’ORI AKAYIN, AKARA DE’EGUN tabi
AKARA D’ORI AKAYIN, O DE’EGUN.
Akayin ni eni ti eyin enu re ti woo tan, ti ko le je ohun to ba lee tabi gbóorín. Koda akara bo se fele to, tun le lee die lenu arugbo ti ko ni eyin, tabi ti akara ba gbee wonu daradara, arugbo ko ni le je e lajegbadun, niru asiko yi, ofooro ni won maa n fe e je.
LILO; ti nkan ba n lo deede, ti awon asiwaju se nkan naa ti kosi isoro, ti aresa see ti ko huun, ti orangun aga see ti ko kabamo, to wa dori enikan ti ko wa ri bee, yala boya nipa aisi agbara to fun eni be, tabi boya won fi ofin kan dee. Eyi ni wipe igba ti nkan d’ori enikan (akayin), eni ti ko lagbara, ti o lowo, ti o lola, ti o nipo, ti ko je nkankan lawujo) ni nkan yipada.
Baba kan le bi omo mefa, ko ti ran awon marun nile oko, kiru baba yii wa ku tabi ki ise bo lowo re, lai tii ran enikefa, owe yii le waye pe “akara d’ori akayin o de’egun”.
Owe keji ti a o maa gbe yewo loni loo bayii: WONTI WONTI KO L’EYIN, BI EYIN BA JE MEJI, KO SA TI FUNFUN tabi
WONTI WONTI KO L’EYIN, BI EYIN BA JE MEJI KO SA TI LE JE MOSA tabi
WONTI WONTI KO L’EYIN, BI EYIN BA JE MEJI, KO SA TI LE JE OBI, tabi ERAN.
Eyi ni wipe kii se dandan ki eyin po ipo yaa lenu, sugbon ki o se ohun ti a fe ko see.
Kii se pe ki nkan po repete, kii se pe ki omo po jaburata…..sugbon die naa ti eyan ba bii, K’Oluwa je won o jeeyan, ki won yan, ki won yanju.
Ti eyan ba bi omo meji, ti okan je dokita, ti ekeji je noosi, tabi looya, kii i se iyalaya eni to bi mewaa, tokankan o ni laari. Idi niyi ti yoruba fi se akiyesi pe kii se opo nkan lo pin dandan bikose iwulo, anfaani ati laarija re.
A tun le lo owe yii, fun apeere ti a ba wa ninu egbe kan ti opolopo awon to wa ninu egbe naa ko mu egbe naa ni okunkundun, a le pa owe yii lati fi yewon wipe, ko ba je awa meji pere ni a n se ojuse, iyoku kekere ni, hanti hanti ko l’eyin, bi eyin ko ba ju gaaga meji lo, ko sa ti le gba eran mu.
Toooo, ni hain ni a o ti danu duro fun ti toni, gegebi a se mon wipe agbala imo ati ooye ni aafin olumoye, aaye wa fun afikun, atunse tabi ayokuro ki o le ba je eko fun gbogbo wa, eyin eyan wa, eyin naa e gbiyanju ki e funwa ni awon owe ti itumo ati lilo re fi ara jo iru owe ti a naa si afefe yii o ki a le ba tun ri ogbon ati imo kan diimu nibe. E seun

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

taniolohun

Esin Ajeji Pelu Ete