Ẹgbẹ́ àwọn àgbààgbà Oòduà (Yorùbá) ní Osinbajo kò gbọdọ̀ kọ̀wé fipò ẹ̀ sílẹ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Èyí ò tófò, kò tófò,fìlà aráabí kù rébété, Kemi Adeoṣun lọ , orí ló kó Adebayọ Shittu yọ,tó fi rí sáa àkọ́kọ́ lò já.Ní báyìí, ó jọ n bí rẹ́kọ̀dù ìgbákejì Ààrẹ ló kàn báyìí,bí
ọ̀rọ̀ se ń bá mokó morò bọ̀ lórí aáwọ tó ń ṣẹlẹ̀ láàrin igbákejì Ààrẹ, Yemi Osinbajo àtawọn kan nílé iṣẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà.
Ẹgbẹ́ àgbààgbà nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá), YCE ló rọ igbákejì Ààrẹ wí pé kó má kọ̀wé fi ipò rẹ̀ sílẹ̀.
Bákan náà ni ẹgbẹ́ YCE rọ Ààrẹ Muhammadu Buhari pé kó má ṣe gbọ́ ohun táwọn kan ń sọ fún un lórí ọ̀rọ̀ Osinbajo wí pé kò rántí bí Osinbajo ṣe dúró tìì láti ìgbà tí wọ́n ti jọ bẹ̀rẹ̀.
Lọ́jọ́ Ẹ̀tì ni iléeṣẹ́ Ààrẹ fìdíi rẹ̀ múlẹ̀ pé Ààrẹ Muhammadu Buhari ló pàṣẹ ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́ fáwọn olùrànlọ́wọ́ márùndínlógójì ìgbákejì Ààrẹ Osinbajo.
Àmọ́ iléeṣẹ́ Ààrẹ ṣàlàyé pé dídá tí wọ́n dá àwọn olùrànlọ́wọ́ Osinbajo dúró ní-ín ṣe pẹ̀lú ìgbìyànjú Ìjọba àpapọ̀ láti dín owó tí Ìjọba ń ná fún ìṣèjọba kù.
àtẹ̀jáde náà ní ọrọ ìdádúró yìí náà ti kọ́kọ́ kan díẹ̀ nínú àwọn olùrànlọ́wọ́ Ààrẹ.
Garba Shehu ní àwọn ipò olóṣèlú kan láwọn ti yọ kúrò tí wọ́n kò sì tún àwọn èèyàn mìíràn yàn sí ipò míì bí Buhari ṣe wọlé lẹ́ẹ̀kejì.
Ó ní kò sí ìjà láàrin Buhari àti Osinabjo lásìkò yìí.
Ṣaájú ni ọ̀gbẹ́ni Laolu akande to jẹ oluranlọwọ fun ìgbákejì Ààrẹ Oṣinbajo ti kọ́kọ́ fi síta pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni pé Ààrẹ Buhari dá àwọn oluranlọwọ Oṣinbajo márùndínlógójì dúró lẹ́nu iṣẹ́ wọn