Home / Art / Àṣà Oòduà / Èsù Óólogbè!
Esu in Yoruba IFA

Èsù Óólogbè!

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, bi a se njade lo loni Eledumare ninu aanu re yio jeki ire oni yi je tiwa Àse.
Laaro yi mofe soro soki nipa èsù òdàrà, o seni laanu lode oni wípé àwon arumoje babalawo ti titori owó ba opolopo nkan je, gbogbo iwa ibaje ti won ti wù nitori owó le sokunkun siwa loju loni sugbon asiri won yio tu leyin ti won ba pa ipo da tabi ni odun die si asiko ti a wa yi.

Ti aba maa so otito funrawa laisi etan rara, opolopo ninu àwon ti a npe ni olori wa ninu esin abalaye yi gan ni obayeje nitori owó ti won fe pa lati fi bo ikun won, eleyi lo fa ti won se nko àwon oyinbo ni eko iro, die ninu àwon ti a npe ni olori yi ni a le toka si gegebi olotito ati olukoni to dangajia, sugbon pupo lo je onimonafiki ninu won, sugbon bope boya asiri yio o tu si gbangba ita.

Nigba miran, elomiran le maa wo òrò mi gegebi aseju sugbon eni to loye koni foju ibe woran nitori emi fe ki otito maa joba nibi gbogbo botile je wípé otito òrò maa nkoro leti àwon obayeje eniyan.
Mo se akiyesi nipa àwon eko iró, ifá iró tite ati orisa ayederu ti àwon babalawo ati olorisa wa ayé ode oni nse fun àwon eniyan paapajulo àwon oyinbo loke okun, gbogbo eleyi ko bojumu, se nitori owó yi naa ni? Bee ifá sofun wa wípé bi a lówó bi a lórò ko sope ki a ma ku tabi ya were, otito ati ododo lo maa mu ki igbeyin omo eda dara laye.

Ni bi odun melo kan seyi ni moti nse akiyesi nipa èsù orisirisi ti àwon babalawo wa to loruko nse lode oni fun àwon omo awo won, paapajulo fun àwon ara òkè okun, botileje wípé emi náà ti ri iru àwon èsù bee lodo àwon onijibiti afamolori fodakun ninu eko yi, orisirisi iwe ifá to je wípé seni won se adako ifá inu iwe elomiran papo mora won ti won nta ti won si npe ni iwe won, emi wo wípé eleyi ko bojumu to, èsù òdàrà je nkan ti babalawo to ba keko yanju to si mo nkan to nse gbudo ni sile re, gegebi a se mo wípé èsù òdàrà je olotito ore, omo ise tabi oluran nise fun òrúnmìlà gegebi opolopo odù se fi idi re mule ju gbogbo omo irunmole toku lo.

Babalawo to keko yanju si gbudo mo okodoro èsù gidi laiki nse sigidi yepe ti won nmo kiri, yangi inu omi ti ki ngbe ni babalawo ma nfi se èsù osetura ti won nbo nigbati ti ifá ba toka wípé kan bo èsù tabi ki won gbe etutu sidi re, sugbon lode oni àwon babalawo ti sori nkan kodo latari owó ojiji ti won nwa kiri.

Èsù orisirisi lo wa ti ise won si yato sira won, èsù osetura ni èsù to je wípé yangi ojulowo ti inu odo ni a fi se ti a si gbudo tefa osetura si nigbati a ba nwe ninu agbo ewe ayajo ifá to loruko, èsù ìjà/aseta si tu wa bakanna toje wípé ise ìjà tabi isora nikan ni ao maa ran, èsù awure náà si tun wa toje wípé ise ki a laje nikan ni ao maa ran to si je wípé gbogbo won ni won lodu ifá to feyinti won, sugbon kayefi die lo je funmi nigbati mo ngbo oruko àwon èsù ti won nse fun àwon omo awo won, bi ; òdàrà, láàlú, elegbara(ti àwon òkè okun npe ni elegua) ni eleyi to je wípé ninu ara oriki èsù ni àwon oruko wonyi, ti a ba maa pe èsù oruko odù ifá ti won fi se loye ki a maa fi pe àwon èsù yi gegebi a se mo wípé oriki èsù ni lasan ni òdàrà, láàlú ati elegbara, sugbon àwon èsù osetura, èsù owonrinsogbe, èsù osalogbe, èsù ogbedi, otura alaketu…..

Akiyesi ti a gbudo se ninu àwon èsù yi ni wípé, yangi nikan lo le jise lairose ko sibiti èsù oni yangi ko le wo yala inu omi ni tabi inu ina, sugbon àwon èsù amò(yepe) ko le wonu omi, to ba wonu omi ibe ni yio pari ise si, sugbon mi o ni soro pupo loni ki a fi di ojó miran.
Èsù òdàrà dara lati ni nitori iwulo re po ti a ba le maa pese fun loorekoore, yio maa dari ire sodo wa yio si maa bawa segun àwon ota wa.
E jeki a gbo nkan ti odù ifá mimo osa elesu so nipa iwulo èsù.
Ifá náà ki bayi wípé:
Agbe woroworo moko
Moko rainrain
Òrùlé sèkèrè komo irunmole seyin jo rainrain a difa fun èsù òdàrà eyiti yio duro siwaju ile ti yio maa dari ire si Òrúnmìlà, Òrúnmìlà ni foju ekun serahun ire gbogbo, Òrúnmìlà lo koke ìpònrí re ru nkan ti òun maa se ti òun yio fi ri ire, won ni ko lo ni obì meji……..ki o maa fi bo èsù, Òrúnmìlà kabomora o rúbo won se sise ifá fun bi èsù òdàrà se gba ebo re niyen, èsù òdàrà wa duro siwaju ile o wa ndari ire sodo Òrúnmìlà, Òrúnmìlà di olowo o di oloro o bere sini njo o nyo o nyin babalawo àwon babalawo nyin ifá, ifá nyin Eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifá wa bami larusegun arusegun ni a nbawo lese obarisa.
Òrúnmìlà ba fiyere ohun bonu wípé;
Èsù mèibì o
Gbooro
Èsù mèibì
Gbooro
Èsù nbi ajé
Gbooro
Èsù mèibì
Gbooro
Èsù nbi aya
Gbooro
Èsù mèibì
Gbooro
Ire gbogbo lesu nbi
Gbooro
Èsù mèibì
Gbooro!
Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wípé èsù yio dari ajé rere siwa loni, èsù òdàrà koni dina ire wa, èsù yio dide loju ona ire wa gbogbo to joko si, aanu yio to wa wa loni o aaase.
Èsù óólogbè!
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.

Continue after the page break for English Version

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

esu

#EsuIsNotSatan: Who Is Esu? What Are The Meanings Of The Words ‘Esu’ And ‘Elegbara’?

This video explains, with sufficient examples, the meaning of the words ‘esu’ and ‘elegbara’. It tells Sis exactly who Esu is in the Yoruba pantheon of the orisa and also gives insight into the characters of the children called Idowu and Alaba. There is a place in Lagos named Ojuelegba, this video tells us why that is. You can learn more about the world of the orisa in my course titled BECOMING YORUBA. Use this link to purchase yours: https://selar.co/262626 ...