Home / Art / Àṣà Oòduà / Ewi Toni – 20.03.2016
Yoruba Festival

Ewi Toni – 20.03.2016

Ojumo ti mo
Eda ti ji saye
Eda ti ko mose asela
Ka ji ni kutu hai
Ka gbegba pota
Iya Akanke nko
O ti re werenjeje
Baba Talabi da
O ti sare re kutuwenji
Ki ni n le wa?
A ni ki tie ni awa omo eniyan n ba kaye?
Atilowo lowo o fagbara
Atila o pile fa kirakita
Eda a sare owo titi
Ati roju founje bonu inira ni
Ani ati woso to gbajumo yoo deewo
Gbogbo pakaleke
Gbogbo furukankan furukankan
E jowo eyin omoran
Lori kini
Olowo to sare owo titi
TEdumare wa bola fun
To wa lowo ohun tan
Ti o le fara bale nawo
Gbogbo ere ti n sa ni pe:
Ki n lowo ju Lamorin
Bi mo lowo ju Lamorin
Ki n la ki n lu
Ju ti Baba isale oro lo
Sugbon igbagbe to salakan ti ko fi lori tomo
eeyan n ba ka
Ere aiku Lahun sa to fi dera e mo posi
Bo ba se po ranti ni
I ba ranti pe ibi gbogbo lowo iku de
Olowo to lowo tan
Ti ko le sinmi ara taare
Eekan laya n ri o soju losoose
Awon tile ti gba kadara kanpa
Ariwo owo nii pa kaye
Eda gbagbe wi pe
Aye la bowo
Bo pe bo ya
Owo taa ni lowo
Owo olowo kuku ni
Ka roju sare mo niwon
Mo fe lowo bi olowo kan oke ohun
Mo fe kole to lalewu
Mo fe jaye oloba
Bi I ti karuna
E da ranti pe
Ojo iku ba de
Ko kuku ni gbowo oya
Ojo tAlimuntu ba wole
Ko ni beere abetele
Olowo to lowo tan
Ko tun le fowo saanu
Se lo n wo talika bii ko ku
Talika gan-an n lowo bii koro re o danu
Ija olowo pelu talika
Adesoye Omolasoye Akewi irorun ni:
Boya ni o ni dorun alakeji ko to pin
E ni ti yoo laye
Bo ba n tewe dandan ni kowo de
Eeyan ti ko si yanri owo lodo alagbede orun
Bi wo fun in ni kokori ile owo
Yoo ju nu
Sare owo mo niwon ore wa
Awa o kuku ni o ma gbiyanju
Ki ni ko soko fonle
A ji le tente enu
Abete tipiri
A ji nasee le Gbalaja
Ounje rasirasi ni e fonle je
Emi o wi pe o ma sise
Akewi imora!
Ka sare ola mo niwonba
Laso imoran ti n fe lele lara ti wa
Gbogbo bo ti wu ka lowo to
A kuku ni mu eepinni de jinnisa.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

ewi

Video: Ewi Rendition

@oluwavalu: We made this video for U.K based musical Artiste @caleb_kunle It was shot during the Covid-19 lockdown in Oworo and i am proud at what we were able to achieve given the little resources at hand then. I Directed this and was assisted by @coolestafrican_kid and @mrbukolajimoh who also iss the D.O.P and Editor of the project. @panafricanmusic just published the video on their YouTube page, go follow the link on @calebkunle‘s Instagram Bio to view the video. Shout out to my main people all ...