Home / Art / Àṣà Oòduà / Ewu Gereye – Adeyanju Ahmed Akewi Imoran
asa yoruba

Ewu Gereye – Adeyanju Ahmed Akewi Imoran

Iya nii je ta ni moo ri,
Owo tabua nii je mo ba o tan
Igba taa ba n wo sokoto penpe
Baye ba ko ni lona
Won le moju fira bi eni ofo se
Boo rokele atata bu
Aye kii rini
Ojo iku kakun mole
Ode o ni saroye
Ojo ikun ba jeko lo
Lode n korin olori ibu kii gbele
Igba toju ba ro koko
Edumare nikan nii duro tini
Lojo ogun ba le
Eni to ba roju rose die
Aje wi pe o nihun o fa diduro won
Igba a ba se kekere
Aye o fi bee yeni taara
Gbogbo ohun ti n be lagbari
O kuku ju ka rihun je kinu o yo bobina
Ase baa se n dagba loye aye n ye ni
Asaye ju ka jeyan jeresi
Bo ba wa dale ka sere osupa
Boju boju oloro n bo,
A ni asaye koja ka sere Ekun n meran
Bojo se n kanri la n ranti pe:
Ere okoto sise koja ka ganra eni nigo
Ere aarin o see fi bee se ni majesin
Baa se n gbegba Agba laye n safihan ara re!
Gbogbo akoko wonyi
Asaye n fara pamo ni
Ohun ti n be ninu aye koja afenuroyin
Igba ewu eniyan ba se gereye lomo araye n rini
Won a wa maa gbemu
Won a wa maa sopakoluke
Ojulumo ti n sa fun ni
Nigba sokoto penpe
Won a wa maa posese oyaya
Boo ranti igba ewu penpe to fajuro die binti
Won a wa maa gbogun
Won a kuku sole alawo dilee won
Ayafi kedumare o gba ni
Ewu gereye lara n ri
Ojo a ba wa ranti igba kan igba kan
Taa rora jaye ferejogi
Won a tun maa gbogun
Ki laye ohun tile duro le na?
Bi mo ba reni pe mi sakiyesi oro
Aye to duro taa le titi ta o ba
Bao lowo lowo ogun ni
Baa lowo ohun tan kiki ijogban
Edumare nikan nii koni yo
Ewu gereye to se e dabora
Mo lohoun lomo aye n sa si labe
Nnkan loro aye
Afi ka gba suuru.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti