Home / Art / Àṣà Oòduà / Fi odu ifa mimo OTURUPONDI dupe oore lowo Olodumare
opn ifa

Fi odu ifa mimo OTURUPONDI dupe oore lowo Olodumare

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku odun aku iyedun emin wa yio se pupo re laye ninu ola ati alaafia ara o ase.
Mo se ni iwure laaro yi wipe gbogbo ohun ti a lelele lodun to koja lo ti owo wa ko to ninu odun tuntun yi gbogbo re ni ao se lase yori lase lowo eledumare a si tun dupe lowo Oba adeda fun aanu re lori wa lati kawa ye dojo oni.
Laaro yi emi yio fi odu ifa mimo OTURUPONDI dupe oore lowo Olodumare ti o mu emin wa mojo oni.
Ifa naa ki bayi wipe:
Asoni asamodun bi odun ba koja lo ope lo ye ki a da lowo ori a difa fun orisa nla oseremogbo lojo ti baba nlo re dupe lowo eledumare nipa oore to se fun-un won ni ko karaale ebo ni ki o se, obi meji, eyele funfun, otin, igbin ki o maa fi se ike eleda re baba wa kabomora o rubo orisa nla wa dolowo o dolokun o donide o dagba o dogbo o, baba wa se nigbanigba odun laye o wa njo o nyo o nyin awo awon babalawo nyin ifa, ifa naa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu ire sebi jebutu ire ni a nbawo lese obarisa.

 
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ninu odun tuntun yi ao lenu ope ati iyin si eledumare, ao ri tiwa se, emin wa yio se opolopo odun loke eepe ao si rowo fi saye o, gbogbo nkan ti a lelele lodun to koja ti owo wa ko to ni yio rorun funwa lati se ninu odun yi o aseeeee.
ABORU ABORU OOO.

 

English Version:

Continue after the page break.

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

Ori Inu The Ifa Concept of the Inner Self

Ori -Inu: The Ifa Concept of the Inner Self

Ori is the mystery of consciousness, and ori-inu is a mystery within a mystery./ It is the invisible self within the self, or, to use the Yoruba description, it is the self that dances in front of the mat. In this context, the mat is the symbol of the unity of all creation. Ifa teaches that even after we have accessed the center point of our being, the course of individual consciousness, there is a deeper inner layer that remains ...