Home / Art / Àṣà Oòduà / Idile Alayo: E Gbo Bi Atejise Na Ti Lo
yoruba family

Idile Alayo: E Gbo Bi Atejise Na Ti Lo

Mo ki gbogbo wa pata lokunrin ati lobinrin, lomode ati lagba wipe a ku ise oni, a si ku abo sori eto wa eto yin, eto Idile Alayo ti ose yi. E wa nkan fidile tabi ki e gbiyanju fidile nkan, ki a jo gbadun ara wa bi ijebu ti ma n gbadun gari.
Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon Ololufe eto yi ni a o maa ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won lamoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO;

“Olootu mo ki yin pupo o, mo si ki gbogbo awa ololufe eto Idile Aalyo wipe, ibanuje kere o tobi ko ni wo’nu ebi enikookan wa o.
E jowo olootu ati gbogbo eyin ojogbon eto Idile Alayo awon amoran meji kan ni o n se mi kami kami kami ti nko mo eyi ti n o tele ninu re, ni mo ro wipe ki n fi lo eyin baba ati iya mi, paapa julo eyin baba mi nile, tori won ni iriri sagba ogbon. Iyen ni mo se to yin wa loni, ki e ba mi gbe awon oro na yewo ki n le mo eyi ti n o tele gan, se eyin agba ni e kuku wipe “a ma n pejo gbon ni a kii pejo go” ori meji si san ju ori kan lo ni eyin agba wi, toto sebi owe o.

Ose meji seyin ni mo se igbeyawo, emi nikan ni omo okunrin ninu omo marun ti baba mi bi, ki baba mi to jade laye won a maa gba mi lamoran lopo igba lori oro loko-laya, lara awon die ninu oro ti baami ma n so nigbana ti nko le gbagbe ree, nse ni won a ma wipe;-
“Kayode mi, pelu ore ofe Olorun, un o fi o saye lo ni, oniwaju mi ko ni keyin laye, beeni eleyin re ko ni siwaju lase Edumare.

Woo mo wa n fi Olorun be o, maa se jeje o, ranti omo eni ti o nse nibikibi ti o ba n lo o, ju gbogbo re lo ti o ba to akoko ti iwo na yoo di oniyawo rora se o, nitori akoko ti o lewu julo ninu aye eda ni o, ti okunrin ba si ti oniyawo nile igba aye miran sese bere ni, akainiye adanwo ni yoo ma yoju, se o si ri obinrin ti o nwo yen hmmm awon ree esu re ni o, awon gan ni esu ti awa okunrin n wa kiri o, nitori na mo be o rora o, obinrin o se finu han o, jowo mase je ki ife ru bo o loju ki o wa ko gbogbo ile aye re le obinrin lowo o, bi obinrin bimo fun ni ko ni ki won ma pani o, suru ati ogbon ni a fi n soko obinrin, ti o ba ni ogorun nayira lowo nse ni ki o so fun iyawo re wipe adorin nayira ni o ku o ku laye lorun ni o, tori ko ni ya o lenu wipe ti e ba jo na adorin nayira owun tan, obinrin yoo tun beere owo miran ti o si mo wipe kosi owo lowo re mo, idi niyi ti o gbudo maa da bi ogbon, bi be ko ile yin o le toro o.

Obinrin ni obinrin yoo si maa je o, nko ni ki o ma fi ife han si iyawo ati awon omo re sugbon ti a ba n sore nse ni a ma n fi aye ija sile o, oko o kii n je ti baba ati omo ki o ma ni ala o, mase ba obinrin da owo po o, mo fi Olorun be o, mase ba obinrin da owo po o, tori o lewu o, rii daju wipe o ntoju iyawo re bi o ti wa ni ipa re, Olorun yoo ran o se o”
Awon oro wonyi ati opo miran beebe ni baami fi ma n jimi nire ni akoko yen loun, ni bayi baami o si mo, sugbon awon oro yi a maa so si mi lokan lopo igba, bi a ti wa pari ijosin ni ojo isinmi ti o koja yi ni alagba ijo wa pemi ti won si gba mi lamoran pupo, die lara awon oro won ree…..
“Buroda Kayode mo ki yin e ku aseyege o, Olodumare ko ni fi eyin ati idile yin sile o, se e rii, igbe aye tuntun miran ni e sese bere si gbe yi o, ni akoko ti e wa yi, e nilo lati fi suuru kun suuru yin o, tori ati ba obinrin gbe ko rorun, koda awa ti a je iranse Olorun gan, a ma la opolopo nkan koja pelu iyawo wa, tobe jube lo suuru ni gbogbo re gba, ki e wa gbadura fun emi isokan, nitori bibeli wipe “Nigbana ni obinrin yoo si fi iya ati baba re sile, okunrin yoo si fi baba ati iya re sile, awon mejeeji yoo si di okan”.

Isokan ni ohun elo ti n mu idile se aseyori, ohun gbogbo ti e ba n se, e gbudo je ki iyawo yin mo sii, e ko gbudo se ohun kan laisi ilowosi iyawo yin nibe, e je ki iyawo yin mo gbogbo bi e ti to laye ati lorun, e je ki o mo pato iye owo osu yin, koda ti o ba seese ki e maa lo apo ifowopamo kan na, eyi ni yoo mu ife ati isokan ebi yin rinle si, ju gbogbo re lo e mase rewesi ninu adura ti iyawo yin ba se yin e fi ejo re sun fun awn iranse Olorun dipo ti e o ma rojo ebi yin fun awon alaigbagbo, Olorun yoo wa pelu yin o, laipe a o ba yin yo ayo omo ni oruko Jesu Amin.”

Hmmmm bi mo ti dele ni ojo yi ni mo wa n ro awon oro yi si ara won, pasito wipe ti a ba fe se aseyori a nilo ISOKAN ki a maa se ohun gbogbo papo, a gbudo finu tan ara wa, beeni baami wipe obinrin o se finu han, won ni n o gbudo je ki obinrin mo gbogbo asiri mi, awon oro meji wonyi wa n se mi ni kayefi, Se oro pasito ni ki n tele bayi ni abi ti baami, iyen ni mo se ni ki n fi lo eyin ojogbon, paapa julo eyin baami nile ti e ti ngbe pelu obinrin fun odun bi melo kan, ki e jowo la mi loye lori awon oro wonyi, e jowo se gbogbo obinrin ni ko se finu han ni? Se looto ni ko bojumu ki obinrin mo asiri oko re ni? Se looto ni wipe laisi Isokan ebi ko le toro ni? E jowo e la mi loye o”
Hmmmm Oro ree o, Eyin Oloye eniyan, ewo ni ki ogbeni Kayode tele bayi, se oro iranse Olorun ni abi ti oloogbe baba won? Se looto ni wipe obinrin o se finu han ni? Nje ese wa ninu ki iyawo mo bi oko re ti to laye lorun? Nje iyawo tiyin tile month iye owo osu ti e ngba? Se lara ife ni ki oko ati aya maa lo apo ifowopamo kan na bi alagba yi ti so? Ju gbogbo re lo, ti gbonmisi omi o to ba waye laarin lokolaya, se alagba ijo ni o to lati fi ejo sun ni abi ebi enÎ??

About ayangalu

26 comments

  1. Kenny Fasemore

    hmmm..Oro kaunka,lotito o ye ki awon baba wa koko so iriri won sugbon emi a fi ogbon ti omode temikun toripe ojo ti npa igun temi naa ojo ti pe.Ni otito o ye ki oko ati iyawo fi inuhan ara won.Opolopo Awon baba wa lo ni iyawo to ju eyokan lo.Ewo gan nipato ti won lefinu han ninu gbogbo won.Ti won ba fi han okan awon toku nko.Sugbon ninu Idile ti oko ko fe ju eyokanlo.Iru Iwa bayi o se e se.Mima dawo si inu apo iwe kan naa je ounti awon eniyan ti se,koda awon to sunmo olorun ti ko papa se e se.Toripe oko tabi iyawo won a fe se nkan fun awon ebi obi won ti ko ni fe ki ekeji mo si,kete ti o ba ti han si awon obi yi wipe gbogbo nkan to ba fe fun awon,iyawo gbodo mo si,wahala ti de.Eleyi je ki opolopo da asa yi nu nigbatoya.Ti o ba wa je fifi inu han obinrin iye owo ti oko re ni.Baba o paaro,bi awa obinrin se ri niyen.Sugbon okunrin ti o sopato owo osu re fun iyawo e, ama ma se bi won se na ni osoosu ni,eyi de le muja wa.ki olorun ma je ki asi fe,obinrin gidi maba okore so owo na ni ki idagbasoke le tete de bawon.

  2. Kenny Fasemore

    amoran mi fun arakunrin yi ni wipe, akeregbe lo ma so ibi ti a foku si lara oun.ki o koko mo iyawo e daada, toripe aba oko nawo ninakuna wa ninu wa to ma ni dandan nkan to ga lohun fe fun omo ohun nitori KARINI, ti o ba je iru eyan ba yen, ko ma so iyeti o ngba fun, sugbon sa iwo naa o ni yoju si ti e o.Bi o ba se pe e ni. Lotito lakooko ti oko temi so iye to ngba fun emi, ti osu ba pari ma ma beere pe o yen ki o ku iye bayi now…Nigbati o complain mi o ki nbi mo.Emi naa a fenu so bi mo se na owo mi ni ko ju bee lo.A de da nkan pupo po ti a jo ni ogun. Ko de si wahala.

  3. Gbolahan Sotomi

    Kabiesi Eku Ojo Meta Ade Ku Oro Eyan Tii Iya Oba ,olohun O Ni Da Won Da Bukata Won (amin) Oro Re O ,ibere Kabiti Afi Ki Olohun Ko Wa Mo O Dasi ,ki Olohun Ma Fi Igi Gba Wa Lenu .Kabiesi Gege Bo Se Yee Emi Si,ni Aye Igba Ti Baba Arakunrin Yen Awon Oko Loun Se Gbogbo Nkan ,ko Da Bi O Je Sile Kan Won Atun Fun Iyawo Ko Fi Se Irun ,sugbon Laye Isin Yi Oko Ati Iyawo Niwon Jo Npin Owo Ile San ,se Oko Ati Iyawo Ti Won Jo Nse Ojuse Ile Se O Wa Se E se Ki Won Ma Fi Nkan Pamo Fun Rawon Ni ,sugbon To Ba Je Pe Okunri O Ni Bere Yi O Nse Bi Awon Baba Aye Atijo A Je Wipe Ko Tele Oro Baba E , Sugbon To Ba Je Wipe Se Ka Jo Se Ni Won Baduro Aje Wipe Ko Tele Oro Pasito

    • Adekunle Opeyemi

      Baami Gbolahan Sotomi mo ki yin e ku ojo meta o, awon baami nko nile? ibanuje kere o tobi ko ni wonu ebi enikookan wa o, Ase. E see pupo fun amoran yin, sugbon mo ro wipe ti oko ati aya ba tie n pin bukata ile gbo, se o wa pondandan ki won mo iye owo osu enikookan won ni, sebi ki olukuluku ti mu ipin tire sile ni abi??

  4. Gbolahan Sotomi

    Nipa Ti Ifowo Pamo Eyin Okunrin Egbon Bii Ha Kini Mole Fi Ogbon Okunrin We Na Ooo Ewo Mi Mo Nkan Ti Mo Le Fi We ,ki Okunrin Tole Gba Pe Ki Oun Ati Iyawo Jo Ni Akaunti Kan Na Won Ati Mo Wipe Owo Ti Iyawo Yen Ngba Oju Tiwon Lo , Kabiesi Ko Da ,awon Ti Mori Tiwon Ija Ni Won Fi Pari E E Ba Ri Oku

  5. Gbolahan Sotomi

    Ija Ni Won Fi Parie Ni Mo Pari Oro Mi Si

  6. Tony Balogun

    Mo ki olootu eto Odo Iwoyi wipe won tun ku abore si ori eto akonilogbon yi.Bi e se un sare Kir lotun los lati ri wipe e fun awon odo iwoyi ni omi ogbon mu yi, ni agbra Olorun, ile ati ona eyin na ko ni daru.Adura ti emi ma koko se niwipe gbogbo igba ti awon odo wa lokunrin yio ba yan aya. Ki Oba oke ki o ma salai yan aya tiwon fun won. Nitoriwipe bi Olorun ba ti yan fun eda, unse ni oro re yio dabi adun se bi ohun ti Olorun lowo si. Sugbonsa bi Olorun ko ba lowo ninu sise eda, oro re yio dabi Asoro se bi ohun ti Olorun ko fowosi. Olootu, ati Baba ati Pasito Arakunrin yi ni won kuku ri oro so. Gege bi oro yin,iriri sagba ohun gbogbo. Ninu iriri Baba ati iriri Pasito ni awon mejeji fi se wasu fun Arakunrin to sese Fe obinrin sile yi.

    Arakunrin yi ni o ni ile aye re lati gbe ohun si ni o mo bi yio se mu ninu waasu Baba re ati ti pasito ti yio si Jan mejeji po ti yio fi di odindin. Ni akoko Arakunrin yi gbodo koko fi arabale lati mo iru awon iwa ati isesi aya re nitoriwipe bi tokotaya ba Jo wa ni oju ona ti won koi ti gbe ara won sile gege bi loko laya, iwa oniwa ni awon mejeji yio ma hu.Lehin ti Arakunrin yi ba ti se orisirisi adanwo fun aya re ta, igbayi ni yio sese wa mu ninu iriri ti o se akojopo re lati odo Baba ati pasito re. Ti owun na yio fi di oniriri ti owun na yio wa di agbani lamoran. Sungbosa bo ba se bi temi ni, emi kori ohun toburu ninu ki tokotaya fi inu han ara won fun igbepo aye irorun. Too, otan lete oku nikun o Olootu.IRE O.

    • Adekunle Opeyemi

      Baami Tony balogun mo ki yin pupo sa, ile ati ona yin ko ni daru o, mo tun ki yin, e ku igbagbogbo wa lori eto yi, Eledua o ni je ki a wa yin ti o. AMIN. E jowo baami gege bi gbolohun ti e fi pari oro yin, se e fara moo ki oko ati aya maa lo apo ifowopamo kanna???

  7. Omotayo Amire

    Gbogbo eniyan ti odale sugbon kiki eni toba ni iberu Eledua nikan kole dani

  8. Temitayo Adedigba

    E kú ètò o oko ìlú, Olórun kò ní pin yín nípá. Bákannáà ni mo kí àwon àgbà olóye tí wón ti dá sí ètò yìí, ilé enìkòòkan wa kò ní dàrú o. Àwon àgbà bò wón ní bí omo bá se rí lase n se àna rè, kí okùnrin yìí fi ara balè kíyèsí ìwà àti ìse ìyàwó rè kí ó tó wá mú òkan tí ó bá le mú ilé tòrò nínú àbá bàbá rè

  9. Kenny Fasemore

    Hmmm Oluko mi mo ki yin pupo fun amoran olowo iyebiye yi, eyin na o ni sile ya lase Edumare

  10. Kenny Fasemore

    Hmmm Oluko mi mo ki yin pupo fun amoran olowo iyebiye yi, eyin na o ni sile ya lase Edumare

  11. Jamiu Raji Rassaki

    hmmm kabiyesi mokiyin pupo ekun atuse ilu ati kiole dara fun awon omo yoruba atata ile ati ona tiyin na koni darun lase eledunmare amin,oro gidi ni baba omo yi so be oro gidi nani pastor so mofe kiemo wipe awon obirin towa nita bayi kose finun an rara imoran temi nipe tobaje wipe iyawo okurin yi koni ise kankan tose ju kotoju ile pelu awon omo tiwon babi kiomu oro baba e lo nitoripe obirin tikoni ise lowo osoro pupo lati je komo iye owo osun toko gba ati iye ti oko bani lowo nitoripe wahala obirin na yiopoju monilo owo loni monilo owo lola niyio ma sofun oko e nitori na komase finu e an iru iyawo be, ti iyawo ba sise ti oko na sise ti awon mejeji simo iye tiwon gba losun wolelo accout kan papo tiwon ba ba arawon so tiwonsi fowo si larin arawon sugbon ti ija basele ti onikaluku fegba owo tie enikokan yiogba iye toba da sinu accout nitoripe kosi bi oko ati iyawo yioni ife arawon to ti ija kekere koni sele larin won sugbon tiwon bamo owo arawo dada ija na koni po pupo tiwon yio fi parie larin arawo

    • Adekunle Opeyemi

      Baami jamiu raji mo ki yin pupo sa, ile ati ona yin ko ni daru lase Edumare. E jowo sa gege bi oro maami RAJE QOREBAT nipa lilo apo ifowo pamo kan na, se e ro wipe gbogbo iranlowo ti oko ba fe se fun molebi re ni iyawo gbudo maa mo si, tabi gbogbo eyi ti iyawo ba fe se fun awon molebi re ni oko gbudo maa mo si? Tori ti won ba n lo apo ifowo pamo kan na, o ti di dandan ki otun ati osi fowo sii ki owo to jade…..

  12. Jamiu Raji Rassaki

    beni kabiyesi woni lati fi owo si tiwon koba fi owo si ajewipe won oni lo accout kan papo gbogbo iranlowo ti enikokan won bafe se fun ebi e ni yioma mu ninu accout ara e sugbon tiwon ba fi owo si iranlowo ti enikokan bafe se fun ebi e enikeji yiomo si won yiomo iye tiwon yo ati iye toba sekun laisi ija be rara

    • Adekunle Opeyemi

      Ennn e se pupo baami Akeem e jowo sa, se e si wa ro wipe o bojumo to ki o je wipe laisi ifowosi iyawo oko o le se iranlowo fun awon obi ti o ti inu won jade, beeni laisi ifowosi oko iyawo ko le se awon obi re loore???

  13. Jamiu Raji Rassaki

    hmmm kabiyesi mokiyin ti oko bafe se iranlowo fun ebi e ti iyawo koba fi owo si oyeki oko bere lowo iyawo e oun tofa tikofi fowo si iyawo e yiose alaye fun oleje wipe owo ti awon ebi e bere tipoju ni tabi ikan miran beni iyawo na yio bere tobadi asiko ti oko e na won yiofi ife ati suru yanjue laifa wahala kankan

    • Adekunle Opeyemi

      Baami Akeem oro yin kuku ye mi, sugbon ohun ti mo fe mo gan ni wipe, nje o boju mu ki oko tabi aya maa gba ase lowo ara won ki won to le se iranlowo fun awon obi enikookan won??

  14. Jamiu Raji Rassaki

    mokiyin kabiyesi aojire bi adupe lowo eledunmare toba je wipe accout an soso niwonjo lopo oun niwon ko gbogbo owo osun won si enikokan won yiomaso furawon kiwon tol yo owo jade mofe kiemo pe ti oko bagba owo ninu accout tiwon lo laiso fun iyawo e iyawo yio binu beni bi iyawo bagba owo jade laiso fun oko na yiobinu ayafi tioni kaluku balo accout tie loto ni onikaluku yioto raye magba owo e bobase wun

    • Adekunle Opeyemi

      E see pupo baami Akeem ile ati ona tiyin na ko ni daru o

    • Adekunle Opeyemi

      Amoran baba wa ALH OLUSHOLA AMUDA…….MO ki olotu mo si tun ki gbogbo abani da seto ati agbani lamoran Ile ati ona kowa wa ko ni daru, awon agba lo npa Lowe wipe toba koju sie seni kio ta toba si ko eyin sie seni kio ta to bawa ku iwo nikan yara tun Ero ara re pa ni, amoran lasan ni eda le gba ara won omo olori pipe yio si fi laakaye pipe gbe yewo lati mo eyi tio se mulo tiyio si wulo fun igbesi aiye Eni, loro kan sa akuko adie nikan lole ko kaye kapa omo niti abo adie oko ni oko gbodo ma je koda kio kere bi omo ologbo, ogbon erero lafin se oko obinrin ko si si asiri kan laiye ti obinrin ba ba okunrin bo tiko ni pada tu loju ija bee kosi bi ase le se ti ija koni waiye laarin loko laya kiidun ko ma pada Koro feerefe asiri ara obinrin nikan ni won kii fe tu, oko to ba ri ibi fara sin si ni niyi lowo aiya iru oko bee ni aiye nba na oja eponle ati iberu, tu asiri arare fun aiya re ki ojo esin re o ku feerefe bio tiwu koje obinrin ni obinrin yio ma je baba re ti so pupo loro ogbon di owo re ti awon Iran se olorun won yen awon na soro sugbon ibi oro dun si niwon so si yen kiye si ara ogbon sidi owore.

  15. Segun Adewake-up

    Moki olootu ati awon ojogbon ti won ti dasi eto yi, Oba Olorun A lekun lakaye gbogbo yin amin. Amoran ti won fun kayode dara mejeji naa losi dara. Sugbon ni temi o, emi gba lamoran ko tele oro baba e, toripe obirin ni obirin yoo maa je, kosi bi ase le se efo ebelo ti koni run igbe. Awon baba wa jekoye pe, obirin kose di mo inu eru, okurin kokurin toba di obirin mo eru e, fuuuummmm. Woje koye siwaju si pe, awon akoni aye atijo nipase obirin ni opo ninu won ma ti subu, mi koni ki okurin maa fi ife han si iyawo e, sugbon bi aba sun ekun a maa riran o

  16. Adekunle Opeyemi

    Hmmmm. E see pupo alagba Bello ile tiyin na ko ni daru lase Edumare

  17. Kemi Fabode

    Hmmmm otito oro ni baba re ti ba so yen obinrin ko se fi inuran obirin ni esu obirin ni ika mo fi olorun be kayode ko ma se tele oro pasito yen nitori obirin ko se fin inuran ooo

  18. Adekunle Opeyemi

    mo ki yin o, ile tiyin na ko ni daru lase Edumare

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti