Home / Art / Àṣà Oòduà / Idile Alayo – Odun ikerin ree ti mo ti se igbeyawo sugbon…
yoruba

Idile Alayo – Odun ikerin ree ti mo ti se igbeyawo sugbon…

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wipe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Idile Alayo wipe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Idile Alayo ti ose yi. E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.  Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-
“Olootu mo ki yin pupo o, e jowo Isele kan ni o sele si mi ti mo si fe ki e na sori afefe ni abala Idile Alayo ki opo ebi le je anfani re.
Odun ikerin ree ti mo ti se igbeyawo sugbon ojoojumo ni mo ma n da ara mi lebi wipe mo di alaya nile. Sebi ile olorogun ni won ma n pe nile ogun? Hmmm ile mi kii kuku se ile olorogun, sugbon ogun ti nbe nibe fere ju ogun boko haramu ni oke oya lo.
Bi mo lo ibi ise ati pada sile pelu ironu ni, ile ariwo nile mi lojoojumo, ko si ile ojo kan ti yoo mo ti ko ni si gbonmi si omi o too laarin emi ati iyawo mi, koda ko si ogbon ti mo le da sii ti awon ara adugbo ko ni yoju si wa lemeji laarin ose kan.

 
Isele yi wa n fa itiju fun mi, koda mo ti gba awe ati adura lori oro yi boya ogun esu ni sugbon ko si iyato kan. Ohun ti o tie maa n je edun okan fun mi julo ni wipe, opo awon ti won n ba wa pari oro lotun losi ni won ko Ka iwe, beeni emi ati iyawo mi si Ka iwe gboye.
Isele kan ni o wa sele simi ni ose ti o koja, nse ni mo pe ki n to de lati ibi ise, bee si ni sunkere fakere oko ni o se okunfa, bi mo ti de ile ni iyawo mi pa kuru mo mi gege bi ise re, ni o bere si so awon oro kobakungbe si mi, ko si oruko ti arabinrin yi ko pe mi, bi o ti n pe mi ni ako aja abirin osi lese, ni o npe mi ni onirannu, asawo, ati bee bee lo.
Mo gbiyanju lati mu oro yi mora sugbon nigba ti o to akoko kan, nse ni ara mi ko gba oro yi mo. Ni mo wi fun arabinrin yi wipe ki o daa duro nibi ti o baa de yen, bi bee ko… N koi ti dele oro mi ti iyawo mi fi wipe “Bi beeko kini yoo sele? O fe na mi abi? Won o bi metala e re”

 
Metala ti mo gbo yi, koda nko mo igba ti mo da ifoti lu arabinrin yi, katowi katofo awa mejeeji ti ko si gidigbo, Ka to ri iseju die awon ara ile ti wole wa, beeni won la ija yi, ti arabinrin yi si wa n leri leka wipe oku kan yoo ba Olorun nile loni ayafi ti nko ba sun ile. Beeni awon eniyan pa opolopo arowa fun mi, ti won si wipe nko gbudo sun ile lale ojo na tori esu lagbara ko nigbala.

 
Beeni mo gboran si won lenu ti mo si pe egbon mi kan wipe mo nbo lodo won ni ojo na, bi mo ti de ibe ni won bi mi wipe se ko si nkan ? Sugbon mo da won lohun wipe ko si nkan, ile ni o su mi ti mo si ro wipe ki nsun lodo won moju tori adugbo wa lewu pupo lowo yi. Emi ati egbon mi wa ni iyara igbafe ti a n wo ero amohun maworan beeni iyawo won wa ni ile idano ti ngbo ounje, beeni ero ibanisoro egbon mi dun. Ori tabili ti o wa ni iyara ijeun ni ero ibanisoro yi wa, bi egbon mi ti gbo wipe ero ibanisoro won dun, ni won dide kia lati lo gbe ipe owun, nibi ti won ti n se waduwadu ni won ti fi ara gba awo ijeun tuntun mefa ti iyawo won sese ra, beeni awon awo yi subu lule ti won si fo.

 
Egbon mi ko ranti ero ibanisoro ti o ndun mo, nse ni won bere mole ti won si n sa eefo awo wonyi, ibi ti emi pelu ti ngbiyanju lati sunmo won, ni iyawo won ti sure jade lati ile idano, ti o si n wipe “Ife Ife ki lo sele? Bawo ni o se see? Se ko se e lese? Bi arabinrin yi ti n beere awon oro wonyi ni o bere mole ti o si n ba oko re sa eefo awo wonyi. Bi arabinrin yi ti bere mole ni egbon mi wipe ” Ma binu, n o moo mo, ero ibanisoro mi ni ndun, ti mo si ni ki n sure gbee, ni ara mi si gba aa” beeni arabinrin yi daun ti o si wipe “Eyin gan ni ki e ma binu, Ka tie dupe wipe ko se yin lese, tori ibi ti o ye ki n gbee si ko ni eyi, emi ni mo se asise”

 
Bi awon mejeeji ti ntakun oro so ni mo di dindinrin si iduro, kayefi ni oro awon mejeeji je simi, tori toba se ile mi ni Hmmmm a o ti ranse si iyanla iya ara wa. Bi mo ti n woye ni o dabi eni wipe mo ri baba agba kan ti o duro si iwaju mi, ti o si n ba mi soro bayi wipe.
“Se o raye lode bayi? Idi ti mo fi mu o wa sibi loni gan ree, oro ebi re kii se oro awe tabi adura, iyato kansoso ni o wa laarin ebi yi ati ebi re, iyato owun ni wipe, ninu ebi yi AWON MEJEEJI NI WON MA N JEBI tosi je wipe ninu ebi tie EYIN MEJEEJI NI E MAA N JARE. Enn se oga meji o si le gbe idiko, agbo meji o le mumi po ninu koto kanna, ti a ba ro oodo po mo oodo, oodo ni yoo fun wa. Isoro kansoso ti nyo ebi e lenu ree, ojo ti olukuluku yin ba bere sii gba asise re, ojo na ni ayo yoo wonu ebi yin wa. Abo oro ni a n so fun omoluabi, toba denu re yoo di odindin. IRE O”

 
Beeni mo ta giri, ni egbon mi si bimi wipe, ki ni o nro se ko si nkan? Mo si da won lohun wipe ko si nkan o. Bi mo ti pada sile ni ojo ikeji, riri ti iyawo mi rimi ni o bere si bu ramuramu, afi bi kiniun ti o fe je ounje aaro. Bi arabinrin yi ti n pariwo ni mo bere si bee pelu ohun tutu ti mo si n toro aforiji lowo re, iyalenu ni o je fun mi bi arabinrin yi ti di mi mu ti o si bu sekun, ti ohun pelu si bere sii be mi. Lati akoko yi ni a ti bere siii gbe ninu isokan ti alafia si joba sinu ebi wa.

 
Mo wa ro wipe oro yi yoo se opolopo ebi ni anfani tori mo mo wipe opo ebi ni won nla iru ipo yi koja, gbolohun MA BINU lagbara ju egbegberun awiye wiye lo ninu ebi. Eledua o ni je ki ebi alayo enikookan wa di ebi ibanuje o. Ase”
Hmmmmm Ase looto ni oro awon agba ti won wipe” TI IYAWO BA JE AGUTAN KI OKO JE EWURE” beeni won wipe SUURU NI A FI N SOKO OBINRIN “KI Eledua ranwa se o, koda oro yi ba idile temi pelu wi, tori emi gan lagidi die, sugbon ni bayi n o se atunse, ki Eledua ran idile enikookan wa lowo ki a ma fi owo ara wa le ife, isokan ati idunnu jina nile wa o.

Ase

 

Abel Simeon Oluwafemi

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti