Ìjàm̀bá iná se ò̩nà Eko sí Ibadan ati Ibadan sí Eko pa
Ìròyìn láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí
Oro gbogbo kii se lori alabahun ni opopona Eko si Ibadan ati Ibadan si Eko. Lati igba ti awon Julius Berger ti bere ona naa ni titun se ni isolenu re ti po sii.
Ijeeje to o koja yii ni oko ajagbe eleru kan dede dubu ona ti moto kankan ko le wole bee si ni ko si eyi to le jade fun bii wakati mefa gbako.
Nnkan bii aago meje aabo ale oni naa ni ajagbe oko agbepo Kan tun gbana ti ko si oko to le koja lo Ibadan tabi wo Eko fun wakati kan gbako.
Opelope awon eso FRSC ati awon panapana ti won tete ji giri si oro naa.
Won bere si ni dari oko lati agbegbe ile epo Fagbems ti o je ibere Long bridge ti ko jinna lopo si ibi ti isele naa ti sele.
Eyo si mu ki gbogbo oko to n wo Eko ati eyi to n jade maa pin ona kan gba.
Ki Eledua so wa nibi ina leralera yii.