Ìjọba ṣe tán láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbowó orí lóri ìbáraẹnisọ̀rọ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àbùùbùtán oore lọ̀rọ̀ sísọ jẹ́ ,fáwa ọmọ aádámọ̀,ọ̀làjú àsìkó yìí,ti fẹ́ mú kí nǹkan ó gbọ̀nà ọ̀tun yọ,bí ó ti jẹ́ pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀èdè yìí yóò máa same lórí ìpè e won.
Álága ilé iṣẹ́ tó ń gbowó orí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà (FIRS), Babatunde Fowler ti ní báyìí o, kò sí nǹkan tó buru nínú kí ìjọba máá gba owó orí fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ.
Fowler sọ èyí di mímọ lásìkò tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé àpérò ètò ọ̀rọ̀ ajé Nàìjíríà tó wáye nilu Abuja.
“Ẹ jẹ́ kí ń sọ báyìí, Ọmọ Nàìjíríà máa ń sọ̀rọ̀ púpọ̀ jùlọ, wọ́n a máa sọ̀rọ̀ ju bo ṣe yẹ ki wọ́n sọ̀rọ̀ lọ, ẹni tó bá sì lágbàra láti sọ̀rọ̀ tó bi wọ́n ṣe ń sọ yìí, tí a bá gbé owo ori lée, kò láìfí”
“A máa fi ara wa wé àwọn orilẹ̀-ède tó ti tó tán, ṣùgbọ́n ìdá méji nínú ìdá ọgọ́rùn ni Ghana ń gba lówó orí fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀, wọ́n sí máa ń lo nǹkan ti wọ́n bá ri níbẹ̀ láti gb bùkáta àwọn fásìtì wọ́n, èyí si lo mú kí àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ máa kawe ni Ghana.”
Fowler tún ṣàlàyé lóri owó ori ti wọn fi le ọjà rírà lori ayélujara pé gbogbo àwọn tí wọn ń lo ayelujara láti ta ọjà wọ́n ni àwọn báńkì yóò máa yọ ìdámarun nínú nǹkan tí wọ́n bá ta, láti fi sọ̀wọ si FIRS.