Home / Art / Àṣà Oòduà / Ìjọba àpapọ̀ f’ẹ́ já iná mànàmáná orílẹ̀èdè Togo àti Benin Republic nítorí gbèsè $7m
Phcn nepa

Ìjọba àpapọ̀ f’ẹ́ já iná mànàmáná orílẹ̀èdè Togo àti Benin Republic nítorí gbèsè $7m

Ìjọba àpapọ̀ f’ẹ́ já iná mànàmáná orílẹ̀èdè Togo àti Benin Republic nítorí gbèsè $7m

Ariwo t’íjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ń pa lé àwọn tó jẹ ẹ́ ni gbèsè owó iná nìyí báyìí o.

Ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí kìí ṣe àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nìjọba àpapọ̀ ń bá wí, bíkòṣe àwọn Ìjọba orílẹ̀-èdè méjì kan lẹ́kùn ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Áfírìkà.

Bẹ́ẹ̀ ni, Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ti jáwé ìkìlọ̀ ránṣẹ́ s’órílẹ̀èdè Togo àti Benin Republic pé kí Ìjọba ibẹ̀ tètè san gbèsè iná ẹ̀lẹ́ńtírìkì tí wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Hmmm… Alága àjọ àpapọ̀ iná mànamáná lẹ́kùn ìwọ oòrùn ilẹ̀ Afirika, Usman Gur Mohammed ni orílẹ̀-èdè méjéèjì yí jẹ Nàìjíríà lówó iná tó tó mílíọ̀nù méje dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ($7m).

Ọ̀gbẹ́ni Miohammed ní òun ò le joyè akótilétà tí yóó máa yan àwọn ọmọ Nàìjíríà jẹ lórí ọ̀rọ̀ iná ọba.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, ‘Ọgọ́rùn mílíọ̀nù dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ($100m) ni orílẹ̀-èdè Benin àti Togo ń jẹ ní gbèsè owó iná nígbà tí mo dé ipò Alága àjọ apínná ọba Nàìjíríà, TCN. Ní báyìí mo ti gba owó náà ku mílíọ̀nù méje dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ($7m).”

Owó iná tí orílẹ̀-èdè Niger republic ní tirẹ̀ ń jẹ dín díẹ̀ ní mílíọ̀nù méjì dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ($2m). A ò sì ní fi wọ́n sílẹ̀. A máa já iná wọn gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń já iná àwọn èèyàn ní Nàìjíríà níbí ni.”

Ó ní kò sójú àánú lọ́rọ̀ iná ọba lílò àti pé, kò ní sí ààyè fún àwọn èèyàn láti máa lo iná ẹ̀lẹ́ńtírìkì orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láì san owó rẹ̀.

Ní kété táwọn ọmọ Nàìjíríà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, onírúurú èsì ni wọ́n ti ń fọ̀ lórí rẹ̀.

Àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ń tara ni pé inú àwọn kò dùn sí Ìròyìn náà nítorí pé ó ní n tí ojú àwọn ọmọ Nàìjíríà tó jẹ owó díẹ̀ lásán ń rí lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ amúnáwá eléyìí tó fihàn pé Ìjọba àpapọ̀ kìí ṣe irú rẹ̀ fún àwọn ilẹ̀ òkèèrè tó jẹ ẹ́ ní gbèsè owó iná.

Bákan náà láwọn kan kọminú pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò le è pèsè iná tó dúró déédé fún àwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ oníǹkan, ṣùgbọ́n ó leè máa pèsè iná ológeere fáwọn ti ilẹ̀ mìíràn tó sì jẹ́ pé lẹ́yìn ò rẹyìn wọn kò ní san owó iná náà.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

Are you showing appreciation?

Ifa still gives blessing like it used toOsun still give children like she used toOgun still make way like he used toSango still gives victory like he used toOsanyin still heal like beforeObatala still purify ones life like beforeYemoja still cares for us as alwaysAje(wealth) still visit like it used toOlokun still gives richness like always.All the Orisa/Irunmole still show their supports, love, care, kindness and blessing to us as they always do.But the question is, Are you showing appreciation?In ...