Ìlé ẹjọ́ rọ Obalufẹ̀ ti Ilé Ifẹ̀ lóyè
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ó dà bí ẹni pé awuyewuye ìfinijoyè , ìyọnilóyè sì ń tẹ̀ẹ́wájú o , bí Ilé ẹjọ́ gíga ti ìpínlẹ Ọṣun ti pa á láṣẹ fún Ọbalúfẹ̀. ti ìlú Ilé Ifẹ̀, Olóyè Idowu Adediwura láti fàpèrè sílẹ̀ kuro lori aga oye rẹ gẹgẹ bii Ọbalúfẹ̀.
Bákan náà Ilé ẹjọ́ yìí tún pa á láṣẹ fún Ọọni Ilé Ifẹ̀, Ọba Adéyẹyè Ògúnwùsì láti tètè dí àlàfo ìyọlóyè yìí ní kíákíá pẹ̀lú ọmọ oye láti ilé oyè Aga láàrin ọjọ́ mọ́kànlélógún.
Ẹni tó kàn lẹ́yìn Ọọni ni Ọbalúfẹ̀ jẹ́. Òun ni Olóòtú Ìjọba Ilé Ifẹ̀.
Agbára tí Ọbalúfẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ kéré sí ti Ọọni torí bí Ọọni kò bá sí nílé, òun ló láṣẹ kódà bí Ọọni bá wà nílé, òun ló ń ṣàkóso àwọn Olóyè ọwọ́ ọ̀tún nígbà tí Ọọni gan ń ṣàmójútó apá kejì.
Adájọ́ tó dá ẹjọ́ náà, Foluke Awolalu àti lórúkọ ilé oyè Aga fi lélẹ̀ pé ìfinijoyè Adediwura kò bá àlàkalẹ̀ òfin ìfinijoyè mu.
Ṣaájú, ilé ẹjọ́ ti wọ́gilé ìwé tí Adediwura fi ṣọwọ́ sí wọn tó ń pè fún kí wọ́n fagilé ẹjọ́ náà nítorí àwọn ẹjọ́ mìíràn wà nílẹ̀ tó so mọ́ ọ̀rọ̀ yìí kan náà.
Ilé ẹjọ́ ní Ìlànà àkọsílẹ̀ ètò ìfinijoyè ní Ilé Ifẹ̀ ti ọdún 1957, ìdílé Aga ló kan láti fa Ọbalúfẹ̀ tuntun kalẹ̀ kìí ṣe ìdílé Àjàǹgbùsìẹkù tí Adediwura tí wọ́n fi joyè ti wá.
Láfikún, ilé ẹjọ́ tún pa á láṣẹ pé Adediwura kò gbọdọ̀ ṣàfihàn ara a rẹ́ kiri bíi Ọbalúfẹ̀ mọ́.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé agbẹjọ́rò Adediwura, Babafemi Akande sàpèjúwe ẹjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí èyí tó tó, tó sì yé yékéyéké. Ó ní ìfinijoyè tó bá ti wà ní àkọsílẹ̀ ti di òfin.
Ẹ̀wẹ̀, “kò sẹ́ni tó kọjá òfin kò si sẹ́ni tó kéré fún òfin. Nítorí náà adájọ́ ti dá ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe là á kalẹ̀”, agbẹjọ́rò Akande sọ bẹ́ẹ̀.