Fẹ́mi Akínṣọlá
Ayé ló bàjẹ́ tí ọmọ olè ń dájọ; oníkálukú mọ ẹ̀tọ́ tó yẹ́’.
Olùṣọ́ àgùtàn Tunde Bakare ṣàlàyé bí ìdámẹ́wàá ṣe bẹ̀rẹ̀ ninu Bíbélì àti pé kò si ẹni tí wọ́n gbé ìbọn tì pé dandan ni kó san ìdámẹ́wàá.
Ó ní iṣẹ́ ọwọ́ òun ni òun ń jẹ nítorí pé Ọlọ́run kìí pe ọ̀lẹ sí iṣẹ́ àlùfáà.
Bakare sọrọ nípa ijọba Muhammadu Buhari pé ó ti gbìyanju, nítorí pé èèyàn ni èèyàn ó máa jẹ́ .
Ó ní àkókò tó fún Buhari láti lọ , kí ẹlòmíì le tẹ̀síwájú láti ibi tí Buhari bá iṣẹ́ dé.
Bákan náà ló mẹ́nuba àjọṣepọ̀ òun àti igbákejì Ààrẹ Ọṣinbajo pé, Ẹ̀gbá méjì kò gbọdọ̀ ja ara wọn níyàn,ni ọ̀rọ̀ àwọn.